Ohun ti Aborisade ṣe fọmọ ọdun mẹsan-an kan lẹyin to fipa ba a lo pọ tan n’Ita-Ogbolu le o

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Bi ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tunji Aboriṣade yii gbọn bii Ifa, koda ko mọ bii ọpẹlẹ, yẹkinni kan ko le yẹ ẹwọn lori rẹ pẹlu bi ko ṣe ri agbalagba ẹgbẹ rẹ ba lo pọ, to jẹ ọmọ ọdun mẹsan-an lo fipa ki mọlẹ to n ba laṣepọ bii pe agbalagba ni, to si tun huwa ẹgbin mi-in pẹlu bo ṣe n fẹnu la oju ara rẹ bii igba ti aja ba n la omi. Ọmọkunrin naa ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ bayii.

ALAROYE gbọ pe ninu ọgba ile-iwe girama to jẹ tawọn ọlọpaa to wa niluu Ita-Ogbolu, n’ijọba ibilẹ Iju/Ita-Ogbolu, ni iṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ọdun yii.

Nigba ti wọn gbe e de kootu lọjọ kẹjọ, oṣu Kejila yii,  Agbefọba, B. B. Ọlanrewaju, ni kayeefi inu iṣẹlẹ ọhun ni bi afurasi ọdaran naa ṣe n fi ẹnu la ẹjẹ to n jade loju ara ọmọdebinrin naa lẹyin to ti fipa ba a lo pọ tan.

Ẹsun meji to fi kan ọkunrin naa lasiko to n fara han nile-ẹjọ giga kan to wa niluu Akurẹ ni pe o fipa ba ọmọde lo pọ, o si tun n fẹnu la a loju ara. Awọn ẹsun yii lo ni o ta ko abala ofin kọkanlelọgbọn ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2007, eyi to wa fun ẹtọ awọn ọmọde.

Ọlanrewaju bẹbẹ pe ki adajọ sun igbẹjọ naa siwaju koun le raaye ko awọn ti yoo jẹrii ta ko olujẹjọ ọhun wa si kootu, niwọn igba to ti yari kanlẹ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Agbẹjọro fun Aborisade, Amofin Tolulọpẹ Adebiyi, rọ adajọ lati siju aanu wo onibaara rẹ, o bẹbẹ pe ki wọn fun un ni beeli, o ni awọn ti ṣetan fun igbẹjọ nigbakiigba ti wọn ba ti fi si.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Yẹmi Fasanmi ni ki ọkunrin ti wọn fẹsun kan ọhun lọọ maa gbatẹgun ninu ọgba ẹwọn Olokuta, titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ati ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun to n bọ ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.

N ni wọn ba sọ ọ bii oko sinu ọkọ awọn ẹlẹwọn to gbe e wa, o di ọgba ẹwọn Olokuta.

Leave a Reply