Ohun ti Mimiko ko le fọdun mẹjọ ṣe, Akeredolu loun ti ṣe e o

“Bo ba ṣe pe ijọba to wa ni ipinlẹ Ondo yii tẹlẹ ṣe daadaa ni, a ba ti ni ibudokọ-oju-omi lọdọ wa nibi yii tipẹ-tipẹ. Ijọba Agagu ti bẹrẹ ẹ, ṣugbọn nigba ti awọn de, wọn pa a ti ni. Bẹẹ naa ni wọn pa ile-ẹkọ gbogbo-nṣe wa, ati awọn nnkan mi-in bẹẹ bẹe yẹn ti lai fọwọ kan an. Gbogbo ohun ti won o le ṣe nigba ti won fi n ṣejọba lawa n ṣe yii, ẹyin naa ẹ wa sibi kẹ ẹ waa woran.” Gomina Rotimi Akeredolu lo n fọwọ sọya bẹẹ niluu Akurẹ.

Asiko to ṣi eto pinpin awọn ohun jijẹ loriṣiriṣị tawọn egbẹ alaaanu kan fi tọrẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa nitori ajakalẹ-arun korona yii lanaa lo n sọ fawọn eeyan pe ijọba oun n ṣe bẹbẹ, bo tilẹ jẹ ko si owo pupọ lati fi ṣe gbogbo ohun to wu awọn lati ṣe. Ṣuga, indomi, makaroni, gari, irẹsi atawọn ohun mi-in wa lara awon ohun ti wọn fẹẹ pin naa, wọn si ni yoo de agboole bii aadọta ẹgbẹrun.

Arakuknrin Akeredolu ni ọpọlọpọ iṣẹ ti ijọba Mimiko to ṣẹṣẹ lọ pa ti, ti wọn ko ṣe, lawọn ti yanju ẹ, ki awọn le mu idẹrun ba awon araalu ni tawọn.

 

Leave a Reply