Ohun ti Tinubu ṣe fun Ambọde l’Ekoo la maa ṣe fun Oyetọla l’Ọṣun – Arẹgbẹṣọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti sọ pe gbogbo nnkan ti Aṣiwaju Bọla Tinubi sọ pe Gomina Oyetọla yoo ṣe lọjọ to n fa a le oun lọwọ lati di gomina ni ko ṣe, bẹẹ ni Tinubu ko pe akiyesi rẹ si i.

Nibi ipade ẹgbẹ APC ẹkun idibo Oriade/Obokun, to waye niluu Ijẹbu-Jeṣa, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Arẹgbẹṣọla, to tun jẹ Minisita fun ọrọ Abẹle lorileede wa ti ṣalaye ọrọ yii

O ni niwọn igba ti Oyetọla ti pa gbogbo ilana ẹgbẹ oṣelu APC ti, oun naa ti pada lẹyin rẹ, o si di dandan ki nnkan to ṣẹlẹ si gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Ambọde, ṣẹlẹ si i.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ti a ba ni ka da a silẹ, ka ṣa a, awa la lẹgbẹ yii, ẹ jẹ ko ye yin daadaa, ẹgbẹ Afẹnifẹre yii, ẹgbẹ onilọsiwaju ni, ẹgbẹ to nifẹẹ ilu, to nifẹẹ araalu, to wa nifẹẹ ara rẹ, ti ki i ṣe pe ka maa foju ṣe e, ree o. Ẹgbẹ Awolọwọ ree o, ẹgbẹ Bọla Ige ree o, ẹgbẹ Baba Akande ree ko too fi wa silẹ diẹ, ẹgbẹ ti a wa ba yin lẹnu ẹ ni 2004 ree, ẹgbẹ ti a fi ipọnju, irora ati inira ko jọ ni 2004 di oṣu Kọkanla, 2010, ti wọn da wa lare ni kootu re o.

“Tori naa, ẹ ma pe ara yin ni igun mọ, ẹyin ni APC, awọn to ti ṣaaju wa lo nilana yii, ti wọn ba tun pada wa sile aye, ibi ti wọn maa wa niyi, wọn o ni i wa si ẹgbẹ ti ki i ṣe tiwọn. O maa ṣoro ki Bọla Ige wa sile aye nisinsinyii ko waa lọ sibomiran, bẹẹ lo maa ṣoro ki Ọbafẹmi Awolọwọ pada waye, ko waa lọ sibomiran ju ibi lọ l’Ọṣun. Awa ti a si ku lori ilẹ naa ti a ko kuro ninu ilana wọn, ibi ti a wa leleyii. Ẹ ko le ri aṣawọ nibi, ẹni ti ẹ ba ri nibi, ẹni ti a jọ bẹrẹ ni, awọn ti wọn tiẹ wa nibi ti wọn ti lọ ri gan-an, a mọ idi ti wọn fi lọ, ko sẹni to wa nibi ti ko ba wa jiya.

“Akọkọ nnkan ti a waa ṣe nibi niyẹn, a pada wale ni o, lati waa da ẹgbẹ wa pada sibi to yẹ ko wa, tori a tẹle ilana awọn ọga wa ti a ro pe eeyan ni wọn, gbogbo ẹmi la fi tẹle wọn, awọn to n wo wa sọ pe ṣe a ki i ṣe Musulumi ni, a ba wọn ṣe gẹgẹ bii ilana ti a ba lọwọ awọn baba wa pe ti o ba wa pẹlu eeyan, ma ṣiyemeji pẹlu ẹ, too ba peeyan lọga rẹ, ma ṣiyemeji pẹlu ẹ, a oo mọ pe awa n leku si wọn, wọn n lejo si wa ni.

“A gbe wọn ju ibi to yẹ ki wọn wa lọ, wọn waa sọ ara wọn di Ọlọrun le wa lori, awa dẹ ti bura, pe ẹnikẹni to ba fi ara rẹ we Ọlọrun nibi ti awa wa, a maa bẹ Ọlọrun pe ki Ọlọrun yẹpẹrẹ rẹ. Ọlọrun sọ pe oun ko lorogun, awa ti ta ko ẹnikẹni to ba fi ara rẹ sipo Ọlọrun, oun niyẹn, Ọlọrun niyẹn.

“Ipọnju, iya to nipọn, ifarada ati iya rẹpẹtẹ la fi to ẹgbẹ yii debi to de yii, oogun bọ, ẹjẹ bọ, ẹmi lọ, o kan wu Ọlọrun lo ni ki awa to ku ma ba a lọ, ki Ọlọrun fori jin awọn to ku, ki Ọlọrun wo ọla ẹmi ti wọn fi ṣe e, ki wọn wọ alujanna.

“Ori kinni yii ni Hassan Ọlajokun ku si o, ori ẹ ni Lash ku si, ori ẹ ni Ayọ Kẹmba ku si, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bo dẹ ṣe le to, aa ko ranro, a gbajọba lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2010, ọjọ keji la kede pe ki ọlọpaa mu ẹnikẹni to ba ranro, gbogbo awọn ti wọn fiya jẹ wa la fa le Ọlọrun lọwọ.

“A waa ṣejọba ọdun mẹjọ, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ nikan lo ri igbadun, gbogbo araalu lo ri igbadun, ko sibi ti ire o de nipinlẹ Ọṣun.

“Nigba ti wọn maa fa ẹni to wa nibẹ bayii le mi lọwọ, laarin oṣu karun-un, tabi oṣu keje, ọdun 2018, wọn ni Rauf, ẹni ti aa duro ti eyi ti o n ṣe leleyii, ẹni ti aa gbesẹ rẹ larugẹ leleyii, ẹni ti ko ni i pana ogo rẹ leleyii, ti ẹni to fa a le mi lọwọ ba n gbọ nnkan ti mo n sọ yii, a maa ro kii ninu ẹ, njẹ o ṣe bẹẹ, nigba ti ko ṣe bẹẹ, ṣe ẹni to fa a le mi lọwọ pe e sakiyesi? Awọn niyẹn, Ọlọrun niyẹn.

“Nnkan mẹta la fi duro sibi ti a wa yii, ti a ba si sootọ pẹlu ẹ, aa ni kabaamọ laelae. Akọkọ ni pe a fẹẹ ran ẹni ti wọn n ṣabosi si lọwọ ko baa le ṣẹgun alabosi. Ekeji, ibi ti a fi awọn ti a fi sijọba si lati tọju araalu, a ko ba wọn nibẹ, ẹni ti ko ba ṣe bẹẹ, awa o le ba a rin, tori ẹnikẹni to ba tako ogunlọgọ awọn araalu, paapaa ju lọ, awọn araalu, Ọlọrun ni ọta oun ni.

“Ti a ba bẹru Ọlọrun, a gbọdọ kuro lọdọ awọn araabi, ki i ṣe ọrọ pe a ko fẹran wọn, a ko le tori tiwọn ta ko Ọlọrun, Ti a ba le mojuto eleyii, a maa bori.

“Ikẹta ni pe gbogbo awọn nnkan ti a ṣe ti awọn araalu n fẹ, ti ọkunrin yii loun o fẹ, to si jẹ koko ẹgbẹ tiwa latigba aye Awolọwọ, aa ni i gba, ki ẹni ti ko tiẹ ye, ba iṣẹ yẹn jẹ, ka si tun gbe e lọwọ, ohun ti a maa ṣe ni pe ka pada lẹyin rẹ.

“Ninu ẹgbẹ, onikaluuku lo lẹtọọ lati ṣe nnkan to ba wu u, ṣugbọn o gbọdọ beere pe ṣe pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ fara mọ nnkan ti o fẹẹ ṣe, abi wọn ko fara mọ ọn. O ṣee ṣe ki gbogbo wọn sun, ki wọn kọri sibikan naa, wọn si le ma fara mọ ọn.

“Bẹẹ lo ṣe ri l’Ekoo lana-an, gomina kan wa nibẹ, o loun fẹẹ lọ si i, ẹgbẹ lawọn o fẹ bẹẹ, wọn fibo le e, bo ṣe ri l’Ekoo lana-an lo ri l’Ọṣun lonii o, ko si bi aja ṣe ṣori ti inaki o ṣe o, ko le waa kan taburo yin nisinyii ki ẹ ni ko ri bẹẹ.

“Awa kọ la bẹrẹ nnkan to wa nilẹ yii, awọn ni wọn bẹrẹ ẹ, wọn dẹ ti bẹrẹ niyẹn, ko maa lọ bẹẹ, Ọlọrun o si ni i fi wa silẹ. Ọlọrun o sọ pe yoo rọrun o, ṣugbọn a maa bori.

“Amọ lori pe awa fi tọkantọkan tẹle awọn ọga, a ṣe ẹtọ wọn fun wọn, awọn ṣabosi wa, a ti waa gba oye ati idaniloju Ọlọrun pe ibi ti a wa yii ni Ọlọrun wa. Ẹ ma pe ara yin ni igun kan mọ o, ojulowo APC ni yin.”

 

Leave a Reply