Florence Babaṣọla
Abẹnugan ileegbimọ aṣofin ana nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Najeem Salam, ti sọ pe pẹlu nnkan to ṣẹlẹ nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC to waye lopin ọsẹ to kọja nipinlẹ Ọṣun, o han gbangba pe ẹgbẹ naa ko mura silẹ fun idibo gomina ti yoo waye lọdun to n bọ.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori oniruuru wahala to ṣẹlẹ kaakiri nibi idibo wọọdu naa lo ti ni o jẹ iyalẹnu fun oun pe Gomina Gboyega Oyetọla ati alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Gboyega Famọọdun, n sa fun idibo, ti wọn fẹẹ fagidi yan awọn eeyan le awọn lori.
O ni nigba ti wọn ba n sa fun idibo to yẹ ko wa ninu ẹgbẹ APC, bawo ni wọn ṣe fẹẹ sọ faraye pe awọn yoo kopa ninu idibo gomina ti yoo waye laarin oniruuru ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ọṣun lọdun 2021.
Salam ṣalaye pe, “Lai si ifohunsọkan nibi kankan laarin awọn lookọ-lookọ, bawo ni ẹnikan yoo ṣe jokoo sọ pe eeyan bayii ni yoo maa dari ẹgbẹ ni wọọdu lai tiẹ fẹẹ mọ boya ẹlomiiran nifẹẹ si ipo yẹn tabi ko sẹni to nifẹẹ si i?
“Awọn ti ẹgbẹ ran wa lati Abuja lati samojuto ibo, ile ijọba ni wọn ko wọn pamọ si, wọn de lọsan-an ọjọ idibo ku ọla, wọn waa sọ pe awọn pepade awọn lookọlookọ ninu ẹgbẹ lai pe iru emi atawọn miran si i, nibẹ ni wọn ti wa n sọ pe awọn ti fẹnuko pe ko ni si idibo.
“Nibo ni wọn ti n ṣeru ẹ? Ni wọọdu temi, gbogbo eto nibamu pẹlu alakalẹ ofin ẹgbẹ wa la tẹle, awọn eeyan wa tu jade daadaa, a si fẹnuko lori awọn ti yoo jẹ oloye wa ni wọọdu, a ko gburoo awọn ti wọn pe ara wọn ni Ileri Oluwa.
“Ẹru idibo lo n ba wọn, awa si mọ pe ẹgbẹ to ni ofin ni ẹgbẹ APC, a gba fọọmu wa taara lati Abuja nigba ti awọn kan ko fọọmu pamọ fun wa l’Ọṣun, a si ti ṣetan lati fi esi idibo wa ṣọwọ si Abuja ti awọn ti olu ile ẹgbẹ ran wa ko ba gba a lọwọ wa.
“Oniluu ko ni i fẹ ko tu. A ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati ba ẹgbẹ wa jẹ. Oniruuru irọ lawọn ti wọn n dari ẹgbẹ l’Ọṣun bayii n pa fun awọn eeyan, bẹẹ ni wọn n dunkooko mọ ẹnikẹni ti ko ba ṣe tiwọn, ṣugbọn agbara ojo o sọ pe oun ko nilee wo, onile ni ko ni i gba fun un.”