Ohun to fa wahala lasiko ibo ti wọn di ni 1964 niyi o (2)

“Nibo la oo gbeyii gba! Ki la oo ti ṣeyi si! Ta ni yoo ba wa yanju ẹ!” Ohun to n ti ẹnu ọpọlọpọ eeyan jade lọjọ naa ree, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 1964. Ohun ti wọn gbọ jọ wọn loju ni. Awọn oniroyin ni wọn gbe e jade lọjọ naa pe ija buruku ti bẹ silẹ laarin ẹni to jẹ olori Naijiria, ati olori ijọba Naijiria. Ẹni ti i ṣe olori Naijiria, ti wọn n pe ni Governor General, ni Ọmọwe Nnamdi Azikiwe. Labẹ ofin, oun lo ni Naijiria, orilẹ-ede rẹ ni, ara to ba si wu u lo le da nibẹ. Oun ni yoo fọwọ si ẹni ti yoo ṣejọba, bi ko ba fọwọ si orukọ ẹnikẹni, tọhun ko le ṣejọba Naijiria. Oun naa ni yoo fi ọwọ si orukọ awọn minisita, nigba ti ẹni to yan gegẹ bii olori ijọba ba ti kọ orukọ awọn minisita to fẹẹ lo ranṣẹ si i. Oun yii kan naa lo si lagbara lati yọ ẹni yoowu ti wọn ba fi ṣe olori Naijiria nipo rẹ, bi iwa onitọhun ko ba tẹ ẹ lọrun mọ.

Ni ti Balewa, oun ni olori Naijiria. Labẹ ofin, gbogbo agbara ijọba pata, abẹ rẹ lo wa, oun naa si ni olori gbogbo awọn ọmọ ogun pata. Oun ni yoo yan ẹni to ba fẹ ko ba oun ṣe minisita, oun naa ni yoo si yan olori awọn ologun gbogbo. Ko si ẹlomiiran to le yan wọn fun un, oun yii nikan naa si ni awọn ologun ati minisita yii gbọdọ maa bẹru, oun naa ni wọn yoo maa gbọ aṣẹ lẹnu rẹ, gbogbo aṣẹ ati agbara olori Naijiria ko ju ko yan ẹni ti yoo ṣe olori ijọba sipo, ko si fọwọ si awọn minisita to ba yan. Ibi kan ti agbara Aarẹ yii le si ni pe o le yọ olori ijọba (Prime Minister) kuro nipo rẹ nigba ti ọrọ ba le patapata tan. Ṣugbọn ki iru eleyii too ṣẹlẹ, ọrọ naa yoo ti le gan-an ni o. Eyi ni pe bii oludamọran agba ni purẹsidenti yii jẹ fun olori ijọba, ko kan gba a nimọran, ko si maa woye ohun ti wọn ba n ṣe ni.

Ṣugbọn purẹsidenti yii ni ijọba orilẹ-ede agbaye maa n saaba ba ṣe, nitori wọn nigbagbọ pe oun lo ni orilẹ-ede rẹ, o si le fi ẹni yoowu to ba wu u ṣe olori ijọba. Ohun to ti dara ṣaa fun iru orilẹ-ede ti wọn ba ti n lo ofin oni-beji bayii ni pe ki awọn mejeeji ti wọn jẹ olori yii, iyẹn olori Naijiria ati olori ijọba jọ wa ni irẹpọ, ki iṣẹ ilu le maa lọ deede bo ti yẹ. Bi ija ba de laarin awọn mejeeji, ọrọ naa le di ogun, o si le tu orilẹ-ede wọn ka. Ohun ti ọkan gbogbo eeyan ṣe ko soke nigba ti wọn gbọ iroyin aramanda naa, pe ija wa laarin Azikiwe, olori Naijiria, ati Balewa, olori ijọba, niyẹn.Ohun to fa ọrọ naa ko ju ọrọ ibo ti wọn fẹẹ di lọjọ keji lọ. Wọn fẹẹ dibo lati yan awọn aṣofn apapọ sile-igbimọ aṣofin Naijiria, awọn yii ni yoo si fa ẹni ti yoo maa ṣe olori Naijiria kalẹ, ko too di pe aarẹ fọwọ si i. Ọrọ ibo naa lo dija laarin Azikiwe ati Balewa.

Awọn ẹgbẹ UPGA ni wọn kọwe si **Esua, olori ajọ to n ṣeto idibo naa pe awọn ko ni i kopa ninu ibo yii, afi ti wọn ba sun ọjọ idibo naa siwaju. Wọn kọwe, ilẹ kun, wọn ni awọn ko mọ idi ti awọn yoo fi kopa ninu idibo naa bi ajọ eleto-idibo naa ko ba ṣe awọn ohun to yẹ ki wọn ṣe. Wọn ni ẹgbẹ NNA ti fi ojooro ba ibo jẹ nigba ti awọn ko tilẹ ti i dibo rara. Wọn ni awọn ẹgbẹ mejeeji to wa ninu NNA yii, ẹgbẹ Dẹmọ ti awọn Akintọla ati NPC ti awọn Sardauna ko gboju le ohun meji ju ojooro ati eru lọ, ki wọn si lo ọlọpaa ati tọọgi lati le awọn ọmọ ẹgbẹ awọn, ati gbogbo awọn ti wọn n fẹ tiwọn lọ. Wọn ni awọn ko ti i dibo, ẹgbẹ awọn Sardauna ti n pariwo pe awọn ti ko gbogbo ọmọ ile-igbimọ aṣofin lati ilẹ Hausa tan pata, bẹẹ ọna kan naa ti wọn fi ṣe eyi ni pe wọn ko jẹ ki fọọmu iforukọsilẹ de ọwọ awọn oludije ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ tawọn. Wọn ni wọn ko gbogbo fọọmu pamọ ni, bi awọn si ti ṣe naa ni Akintọla ati ẹgbẹ Dẹmọ ẹ n ṣe ni West.

Lẹyin ti Azikiwe ti yẹ gbogbo ohun to n lọ yii wo, ti ẹri si wa pe loootọ ni awọn ohun ti awọn UPGA n sọ, pe awọn NNA ko fẹẹ dibo bi wọn ti n dibo, wọn mura lati fi ojooro ati agidi gbe ara wọn wọle ni, paapaa nigba ti awọn UPGA atawọn mi-in ti wa n pe fun isunsiwaju ibo naa, Olori Naijiria naa ro o pe ohun to yẹ ni ṣiṣe ni lati sun ibo naa siwaju loootọ, ki ajọ eleto idibo yii le tun nnkan ṣe, ki wọn si fagi le awọn ohun ti wọn ba ti ṣe ti ko ba ofin mu. Nidii eyi ni Azikiwe ṣe ranṣẹ pe olori ijọba, iyẹn Balewa, pe ki awọn le jọ sọrọ naa kunna. Ṣugbọn ki Balewa too lọ sipade pẹlu Azikiwe, oun ti ba olori ẹgbẹ oṣelu tirẹ, Sardauna, sọrọ ni Kaduna ti iyẹn wa nile ijọba, iyẹn si ti pa a laṣẹ fun un pe ko gbọdọ gba ohun yoowu ti aarẹ ba sọ, to ba   yatọ si pe ki wọn dibo naa lọjọ ti wọn fẹẹ di i. Bẹẹ lọjọ ti wọn n pade yii, ibo ku ọtunla ni.

Ṣugbọn nigba ti wọn pade, gbogbo ohun ti Azikiwe n sọ ni Balewa n yi danu, wọn si fa ọrọ naa titi ti wọn ko fi ribi fi ori rẹ sọ. Nigba naa ni Azikiwe gbe iwe jade lẹyin ipade naa pe ede-aiyede waye laarin oun ati olori ijọba Naijiria loni-in yii o, nitori gbogbo bi oun ti mu amọran wa pe ki awọn sun ọjọ idibo to n bọ siwaju, Balewa ko gba foun, ko gba si oun lẹnu, ko si fi ibẹru oun gegẹ bii olori Naijiria han rara. Fun Aarẹ Nnamdi Azikiwe lati kọ iru ọrọ bayii jade fihan pe wahala gidi wa loootọ niyi, nitori ọrọ ti dija laarin oun ati Olori ijọba niyẹn. Ohun to si jẹ ki gbogbo eeyan kawọ mọri nigba ti wọn gbọ ọrọ yii lọjọ keji niyi, ti ọpọlọpọ eeyan si n sọ pe ṣe ki i ṣe asiko naa ni Naijiria yoo daru kọja atunṣe. Ariwo ti iwe iroyin Daily Times ọjọ keji tọrọ yii ṣẹlẹ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, 1964, naa tilẹ pa le gan-an ni. Niṣe ni wọn lọgun too bayii pe: CRISIS (Rogbodiyan)! Ni wọn ba bẹrẹ si i royin iṣẹlẹ ọhun bayii pe:

“Gbogbo aye lo pariwo lala lanaa si atẹjade ti Aarẹ Nnamdi Azikiwe gbe jade, to fi sọ pe ede-aiyede to lagbara wa laarin oun ati Olori ijọba, Alaaji Tafawa Balewa, lori ọrọ ibo si ile-igbimọ aṣofin apapọ ilẹ wa to yẹ ka di lọla.

“Ni Kaduna, lalẹ ana yii, awọn aṣaaju agba fun ẹgbẹ Northern Peoples’ Cogrerss (NPC) bẹrẹ ipade aṣedoru pẹlu olori ẹgbẹ wọn, Alaaji Ahmadu Bello, ninu ile rẹ ni agbegbe Nassarawa. Ọrọ ede-aiyede yii naa lawọn naa fẹẹ tori ẹ ṣepade o. Awọn agbaagba ẹgbẹ ti wọn wa nibi ipade naa ni Alaaji Hamann Pategi ti ṣe akọwe ẹgbẹ wọn. Alaaji Muhammad Nasir ti i ṣe minisita fun eto idajọ ni Northern Region, ati Alaaji Aliyu Makama Bida ti i ṣe minisita fun eto inawo wọn.    

“Ede aiyede ti lẹta ti aarẹ kọ sita naa le da silẹ ni wọn tori ẹ n ṣepade yii, ṣugbọn titi ti ilẹ fi ṣu pata, wọn ko ti i ri ọrọ naa fi ori rẹ ti sibi kan, bẹẹ ni wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni mọ ohun to n lọ nibi ipade naa ti wọn n ṣe. Ki wọn too bẹrẹ ipade yii ni wọn ti kọkọ fagi le ipolongo nla kan ti ẹgbẹ naa fẹẹ ṣe ni Kaduna yii, nibi ti Sardauna ti n mura lati ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ gẹgẹ bii aṣekagba ipolongo ibo wọn. Ko sẹni to ti i mọ ohun ti yoo jade lẹnu awọn NPC yii, nitori titi alẹ ni wọn ṣi n ṣepade wọn lọ.

“Ni Ẹnugu, ogunlọgọ awọn eeyan ni wọn rọ jade ni tiwọn, Awọn oloṣelu, awọn iyalọja, awọn oṣiṣẹ ọba ati ero pupọ, ariwo ti wọn n pa yi ilu naa ka ni pe ko ni i si ibo kankan lọla ode yii. Ohun ti wọn kọ si ara awọn iwe ti wọn gbe dani ni “No Election! No election!!” Wọn ni awọn ko ni i gba ki ẹnikẹni dibo lọdọ awọn, afi ti ajọ to n ṣeto idibo naa ba ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. Nigba  ti wọn yi ilu po titi, ile ijọba ni wọn fabọ si pẹlu lẹta lọwọ wọn, wọn ni awọn fẹ ki olori ijọba Eastern Region gbe iwe awọn lọ si Eko, nile ijọba apapọ, ki wọn si sọ fawọn ti wọn wa nibẹ  pe ko ni i si idibo lọdọ tawọn nilẹ Ibo, nitori awọn ko le lọ sibi idibo to kun fun eru ati ojooro lati ilẹ.

“Ni Eko, awọn aṣaaju ẹgbẹ UPGA naa ṣe iwọde, wọn si ko ero rẹpẹtẹ lẹyin wọn. Ni **Rowe Park ni wọn ti bẹrẹ, awọn to si ṣaaju wọn ni Ọgbẹni **Mcewen ti i ṣe akọwe ẹgbẹ NCNC, Tunji Ọtẹgbẹyẹ ati Abiọla Oṣodi. Ero to wa lẹyin wọn pọ debii pe awọn mọto ya kuro lọna fun wọn ni, bẹẹ ni wọn si ṣe ba Bamgboṣe kọja, ati awọn adugbo mi-in, titi ti wọn fi de Race Course, ti wọn si n pariwo pe ọdọ Azikiwe lawọn n lọ lati lọọ fẹjọ sun un …!”

Bi iroyin naa ti lọ ree ninu Daily Times. Ibo ku ọla, ko si sẹni to mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ mọ rara. Ṣugbọn lẹẹkan naa, lalẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, 1964 yii, lawọn UPGA tun sare gbe iwe mi-in jade, ninu ẹ ni wọn si ti pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn pe ẹnikẹni ko gbọdọ jade lọọ dibo ninu wọn, bẹẹ ni awọn ti wọn fẹẹ dije du ipo lọ sile igbimọ aṣofin lorukọ UPGA ko gbọdọ kopa ninu idibo naa mọ o, ki wọn fi ẹgbẹ Dẹmọ ti Akintọla ati NPC ti Sardauna silẹ, ki wọn maa da ṣeto idibo wọn. Bẹẹ alẹ ibo ku ọla leleyii ṣẹlẹ, bawo ni wọn yoo waa ti ṣe e. Rogbodiyan nla gan-an si leleyii o!

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply