Ohun to fa wahala lasiko ibo ti wọn di ni 1964 niyi o (3)

Ibo ti daru bayii o. Abi nigba to ṣe pe ni alẹ ọjọ ti ibo ku ọla ni ẹgbẹ UPGA gbe iwe ijade, ti wọn si kilọ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn pata pe ẹnikẹni ko gbọdọ ba wọn dibo naa. Wọn ni ki wọn fi ẹgbẹ NNA ti wọn jẹ apapọ NPC ti awọn Sardauna Ahmadu Bello ati ẹgbẹ Dẹmọ ti Ladoke Akintọla silẹ ki wọn dibo naa bi wọn ba ti fẹ, ṣugbọn ki ọmọ ẹgbẹ UPGA ti wọn jẹ apapọ AG ati NCNC kankan ma ṣe ba wọn da si i. Wọn ni ki wọn jẹ ki wọn yanju gbogbo ẹ lati ọdọ wọn lọhun-un, ibi to ba si yọri si, gbogbo ọmọ Naijiria yoo foju ri i. Ṣugbọn ikilọ naa jọ pe o ti pẹ diẹ, nitori alẹ ọjọ ti ibo ku ọla ni. Idarudapọ lo mu ba ọpọ ọmọ ẹgbẹ AG, ati awọn aṣaaju wọn mi-in, nitori ko si aaye fun awọn olori ẹgbẹ UPGA yii lati ṣe alaye lẹkun-un rẹrẹ fawọn eeyan wọn. Aye ko si ti i di aye foonu bayii tabi ẹrọ ayelujara, nibi ti kaluku ti le mọ ohun to n ṣẹlẹ funra wọn.

Nitori bẹẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn olori ẹgbẹ yii sare, ti awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group ti wọn pọ ju lọ ninu UPGA ilẹ Yoruba n kiri, tawọn NCNC ti wọn jẹ UPGA ilẹ Ibo naa si fi gbogbo oru rin mọju, ọrọ naa ko ri bi wọn ti fẹ rara. Sardauna ati Akintọla pẹlu awọn eeyan tiwọn naa ko fi awọn araalu lọkan balẹ, wọn ko jẹ ki wọn mọ ohun  to n lọ, nitori lalaala ni redio n ke pe ko si ohun to ṣe ibo ti wọn yoo di lọjọ naa, ohun gbogbo n lọ ni mẹlọ-mẹlọ, ki kaluku jade lati waa dibo, ko si ẹni ti yoo mu wọn lọwọ dani lati ma ṣe dibo wọn. Nibi ti awọn araalu ti pin si meji mẹta ree, awọn mi-in ko mọ bi ki awọn waa dibo ni tabi ki awọn ma wa, awọn mi-in ni awọn yoo jade lọọ dibo bo tilẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ UPGA to ni ki wọn ma dibo ni wọn, awọn mi-in si sọ pe ko si eyi to kan awọn ninu ọrọ yii, awọn ko ni nnkan kan ti awọn fẹẹ da si nibẹ.

Ni ọjọ ti ibo ku ọla yii gangan, Olori Naijiria, Aarẹ Nnamdi Azikiwe, tun pe ipade mi-in, lẹyin ti ipade ti oun ati olori ijọba, Tafawa Balewa, ṣe ti fi ori ṣanpọn. Ṣe nigba ti awọn mejeeji pade, ede-aiyede ni wọn ba tuka, Azikiwe si gbe iwe jade lati fi ṣalaye pe ipade ti oun ati Balewa ṣe o, ẹja ni, ki i ṣe akan, awọn ko gbọ ara awọn ye rara. Ṣugbọn oun ti pe ipade awọn olori ijọba gbogbo to ku, pe ki wọn ri oun ni ọjọ ti ibo ku ọla yii naa, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, 1964. Ṣugbọn ipade naa paapaa ko tun lọ geere, nitori awọn mẹwaa lo yẹ ki wọn ṣepade naa, ṣugbọn awọn mẹfa ni wọn wa. Awọn mẹrin ti ko si wa yii, koko ni wọn jẹ, debii pe ko si ohun ti awọn mẹfa to jokoo sibẹ yoo le ṣe. Eto ti Azikiwe, gẹgẹ bii aarẹ, ṣe ni pe ki awọn olori ijọba ipinlẹ kọọkan, ati awọn gomina wọn, jọ maa bọ l’Ekoo, ki wọn waa ba oun ati Balewa.

Eyi ni pe gomina ipinlẹ Mid-West yoo wa, yoo si mu olori ijọba ibẹ dani. Gomina ipinlẹ North, iyẹn ilẹ Huasa, naa yoo wa, yoo si mu Ahmadu Bello dani. Gomina ipinlẹ East yoo wa, yoo si mu Michael Okpara ti i ṣe olori ijọba ibẹ dani. Gomina ilẹ Yoruba naa yoo wa, yoo si mu Ladoke Akintọla to jẹ olori ijọba naa dani. Ṣugbọn nigba ti akoko ipade pe, gomina Mid-West ati olori ijọba rẹ, pẹlu gomina East ati olori ijọba rẹ nikan ni wọn wa. Sardauna ko wa, bẹẹ ni Akintọla naa ko wa, wọn ko si jẹ ki awọn gomina wọn naa wa. Ibinu gbaa ni ọrọ yii jẹ fun Azikiwe, nitori o fi i han bii ẹni ti ko lagbara kan bayii, to jẹ wọn kan fi i di gẹrẹwu lasan ni. Gbogbo alaye ti ipade naa iba mu wa, ti wọn iba ribi yanju ọrọ naa, ko ṣee ṣe. Nigba ti wọn pari ipade, wọn ko tilẹ jẹ ki Azikiwe sọrọ, Balewa lo sọrọ, o si ni ibo naa yoo waye bi wọn ti kọwe ẹ, ko si isunsiwaju kankan.

Gbogbo agbara ti Azikiwe ti ro pe oun yoo ri lo bi ọrọ ba da bayii ni wọn ja gba mọ ọn lọwọ, ọkunrin ti wọn n pe ni aarẹ Naijiria naa si ri i pe korofo lasan loun wa, apa oun ko ka nnkan kan. Azikiwe ti ro pe ti ọrọ ba dija, ti kinni naa ba fẹẹ le, oun le  pe awọn ṣọja tabi ọlọpaa lati le mu aṣẹ ti oun ba pa ṣẹ, ati pe bi Balewa, tabi Sardauna, ati awọn olori ijọba to ba ku ba ti ri eyi, ti wọn ri i pe oun lawọn ọlọpaa ati ṣọja fẹẹ gbọrọ si lẹnu, kia ni wọn yoo ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ rara. Nitori ki wọn too lọ sipade ti Azikiwe pe gbogbo awọn gomina ati olori ijọba ipinlẹ gbogbo si yii, kinni kan ti ṣẹlẹ to sọ idi Azikiwe funra ẹ domi. Azikiwe loun fẹẹ gbamọran, o ranṣẹ si olori awọn ọmọ ogun gbogbo pe ko ri oun, iyẹn ki i ṣe ọmọ  Naijiria, oyinbo loun, ṣugbọn Azikiwe ni ko wa ki oun tiẹ gbọ imọran lẹnu rẹ bi ọrọ ba da bayii.

Ṣugbọn olori awọn ọmọ ogun naa ko lọ, nitori ki oun too le lọ si ọdọ aarẹ bẹẹ, aa jẹ pe olori ijọba lo ni ki oun lọ. Ṣugbọn pẹlu bi ọrọ ṣe wa yii, oun ko le yọju si aarẹ, nitori oun ko ti i gba aṣẹ lati ṣe bẹẹ. Lọrọ kan, olori awọn ọmọ ogun ko yọju si Azikiwe. Eyi ti baba naa ti wọn n pe ni aarẹ yii yoo ri ni pe awọn olori ọmọ ogun ilẹ, iyẹn ṣọja, olori ọmọ ogun ofurufu, ati olori awọn ọlọpaa, gbogbo wọn lọ si ọdọ Balewa, wọn ba a ya fọto lẹyin ti wọn sọrọ tan, lati fi han Azikiwe ati gbogbo ẹni ti ọrọ ko ba ye tẹlẹ pe Balewa nikan lo le fun awọn ni aṣẹ ti awọn yoo tẹle e, ko si ohun to kan awọn kan aarẹ rara. Lati tubọ jẹ ki ọrọ naa ye gbogbo eeyan, awọn ologun naa gbe atẹjade tiwọn sita pe awọn ọmọ ogun Naijiria ti ṣetan lati doju ija kọ ẹni yoowu to ba fẹẹ da eto idibo ti wọn yoo di lọla naa ru, pe ki kaluku jade lati lọọ dibo wọọrọwọ ni, ẹni ti ko ba si dibo, to jẹ o fẹẹ da eto naa ru ni, ohun ti oju ẹ ba ri, ko fara mọ ọn.

Ọrọ naa ye Azikiwe daadaa ju bi awọn ologun yii ti sọ lọ, o mọ pe oun ni wọn n pa owe mọ, paapaa nigba ti Sardauna naa ti pada sọ pe oun ko lọ si ibi ipade ti Azikiwe pe, nitori ipade lati pin Naijiria niya, pe ki kaluku maa ṣe tirẹ lọtọọtọ ni. Eyi ni ko ṣe le ba Balewa jiyan mọ, ti ko si le ba a ṣe agidi kankan. Okpara to wa lati ilẹ Ibo, to si jẹ olori ijọba ibẹ, ati NCNC naa pẹlu UPGA nikan lo n ṣe lodi si ki wọn dibo naa, ṣugbọn olori ijọba Mid-West, Dennis Osadebay, ko ri ohun to buru ninu ki awọn maa ba ibo naa lọ, ohun ti awọn gomina to wa nipade ọhun si n sọ ni pe ẹru n ba awọn, pe ti wọn ba ni ki wọn ma dibo naa, o le da wahala silẹ gan-an ni. Nidii eyi, ko si ohun meji ti wọn le sọ mọ ju pe ki Azikiwe fọwọ si i ki wọn maa lọọ dibo naa, ko si kilọ fun wọn gẹgẹ bii olori ilu pe wọn ko gbọdọ ṣe ohun to lodi sofin.

Ṣugbọn gbogbo ohun ti wọn n ṣe naa lo lodi sofin, o kan jẹ wọn ti ka Azikiwe lọwọ ati ẹnu ko ni, ko si si ohun kan bayii to le ṣe. Ni alẹ ọjọ ti ibo ku ọla yii naa, Sardauna naa ṣepade tirẹ ni Kaduna, pẹlu awọn minista rẹ, ọmọ ẹgbẹ oṣelu NPC kan naa ni gbogbo wọn. Ṣugbọn nigba ti ipade naa n lọ, Sardauna ranṣẹ pe ọrẹ rẹ, iyẹn Ọgagun Sam Ademulẹgun ti i ṣe olori gbogbo awọn ọmọ ogun to wa nilẹ Hausa ati agbegbe rẹ, o ni ko maa bọ nipade awọn, bẹẹ ni wọn si pe Alaaji M. D. Yussuf toun naa jẹ olori ọlọpaa agbegbe naa sibẹ, awọn Sardauna ni awọn fẹẹ mọ boya ko ni i si ewu kan lọrọ idibo naa lati ọdọ wọn. Ademulẹgun ni bo ba ṣe ti ọrọ awọn ṣọja gbogbo nilẹ Hausa ni, ikapa oun ni gbogbo wọn wa, ẹnikẹni to ba si fẹẹ fa wahala kan, yoo ba awọn nibẹ digbi. O ni ki Sardauna fọkan balẹ, ko  ni i si ewu lọrọ ejo, ti ọmọ eku ni yoo ṣoro.

Bayii ni awọn ṣọja bọ si ọwọ Balewa ati Sardauna, nitori ni alẹ ọjọ naa ni awọn ṣọja ti yi gbogbo ile ijọba Eko ati Kaduna ka, ti awọn ṣọja kan si gbe lanrofa bii mẹjọ jade, ti wọn n yi gbogbo ilu po. Ibi mẹta ni awọn ṣọja naa wa: Eko pẹlu Ibadan ati Kaduna. Ijọba apapọ ko ṣọja si Eko digbidigbi, wọn si fun Akintọla naa ni ṣọja ni Ibadan ki wọn le kapa ilẹ Yoruba, Sardauna naa si ko awọn ṣọja mọra ni Kaduna. Bẹẹ ni nnkan ri ni aarọ ọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun 1964, lọjọ ti wọn fẹẹ dibo awọn ti yoo tun ṣejọba Naijiria fun odidi ọdun marun-un mi-in! Ọjọruu lọjọ naa o, ọjọ kan ti ko ṣee gbagbe ninu itan orilẹ-ede Naijiria ni.

Leave a Reply