Ohun to fa wahala lasiko ibo ti wọn di ni 1964 niyi o (4)

Ibo ti wọn di ni Naijiria yii ni ọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun 1964, nnkan ni ibo naa o jare. Loootọ ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ UPGA ti paṣẹ pe ẹnikẹni ninu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ko gbọdọ jade dibo, ṣugbọn segesege lọrọ naa pada bọ si. Idi ni pe ọtọ ni ohun ti UPGA n sọ, ọtọ ni ohun ti awọn ti wọn n ṣejọba n sọ. Ọgbẹni Eyo Esua ti i ṣe alaṣẹ pata fun igbimọ to n ṣeto idibo sọrọ lori redio, ọrọ rẹ si ni gbogbo ileeṣẹ redio n pariwo ju lọ laarin iṣẹju si iṣẹju. Ohu to sọ ni pe ibo ti wọn fẹẹ di ni ọjọ naa ko yẹ, wọn yoo bẹrẹ ibo naa ni aago meje owurọ, wọn yoo si pari rẹ ni aago mẹfa aṣaalẹ, o si n pe gbogbo eeyan pe ki wọn jade lati lọọ dibo wọn. Ijọba awọn Akintọla naa bẹrẹ ariwo tiwọn paapaa lori redio, ti wọn n sọ pe ki gbogbo eeyan nilẹ Yoruba jade lati lọọ dibo, pe ko sẹni kan  ti yoo di wọn lọwọ tabi dena mọ wọn, nitori awọn ọlọpaa ati ṣọja wa nigboro lati fiya nla jẹ ẹni to ba fẹẹ fa wahala kankan.

Bi awọn ti n pariwo nilẹ Yoruba yii, bẹẹ naa ni redio wọn n pariwo nilẹ Hausa, ohun ti awọn naa n wi ni pe ibo n lọ deede o, ko si ẹni ti yoo di wọn lọwọ, ki kaluku jade lati lọọ dibo ni. Awọn yii ko kuku tilẹ ṣẹṣẹ nilo ikede ni tiwọn, wọn ko figba kan gbọ pe UPGA ni ki wọn ma dibo, nitori ko sẹni to sọ iru iyẹn lori redio tiwọn. Awọn fẹẹ dibo nilẹ Hausa, wọn si ti mura silẹ daadaa. Ni Mid-West, olori ijọba ibẹ funra rẹ, Denis Osadebbay, lo n kede lori redio pe ibo naa n lọ bi wọn ti ṣeto rẹ, ki ẹnikẹni ma duro sile lai dibo, ki wọn jade lati lọọ dibo nitori ilọsiwaju gbogbo agbegbe Midwest. Ilẹ Ibo nikan ni redio tiwọn ti n pariwo pe ko ni i si ibo kankan, ki kaluku ma jade. Eyi lo ṣe jẹ pe nigba ti wọn yoo dibo, wọn dibo daadaa nilẹ Hausa ati Midwest, kinni naa ko lọ daadaa to nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo.

Bi awọn ero ko ṣe jade ni ilẹ Yoruba tẹ awọn ti wọn n ṣeto ibo naa ati ijọba Akintọla lọrun daadaa, nitori ni ọpọlọpọ ibi, orukọ ẹni ti wọn ba fẹ ni wọn n ju sibẹ, paapaa nigba to jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ni wọn jade fun ibo naa ju lọ. Awọn ibi ti wọn ba ti le ri i pe awọn eeyan jade, ti ọrọ ibo ibẹ ko si fẹẹ ye wọn, ti wọn n bẹru pe boya ọmọ ẹgbẹ UPGA le wọle ni agbegbe naa, funra wọn, iyẹn awọn tọọgi ijọba ni wọn yoo da eto idibo agbegbe naa ru. Ohun ti wọn ṣe ni Sagamu niyi, nibi ti wọn ti yan Tai Ṣolarin, olukọ agba ni ileewe Mayflower College, gẹgẹ bii oludari agba fun idibo agbegbe naa. Adugbo yii ni iyawo Awolọwọ, Oloye Dideolu Awolọwọ, ti jade lati du ipo lọ sile-igbimọ aṣofin. Bo si tilẹ jẹ pe ẹgbẹ UPGA ni awọn Awolọwọ n ṣe, ti wọn ti ni wọn ko ni i kopa ninu idibo naa, sibẹ, awọn ara Rẹmọ ni awọn yoo dibo awọn fun iyawo Awolọwọ, ko ma di pe awọn Dẹmọ lọọ gbe ẹni kan wọle fawọn.

Eyi lo jẹ ki wọn kopa ninu eto idibo yii, ti wọn si ko gbogbo ibo ti wọn di ni agbegbe Rẹmọ jọ si ileewe Moslem High School. Nigba ti wọn ti ko gbogbo esi idibo jọ sibẹ tan, niṣe lawọn kan de ninu aṣọ ọlọpaa ati aṣọ ṣọja, wọn ni wọn ba bẹrẹ si i ko apoti ibo naa, wọn ni wọn n ko o lọ sibi ti wọn yoo ti ka a daadaa. Eyi ni Tai Ṣolarin tori ẹ yari, nitori o mọ pe awọn ti wọn wa naa ki i ṣe ṣọja, wọn ki i ṣe ọlọpaa, tọọgi oloṣelu ni wọn, afi to ba si jẹ awọn ṣọja ati ọlọpaa naa n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ Dẹmọ. Nigba ti Tai Ṣolarin ko gba ni wọn ṣe lu u daadaa, ti wọn si ko gbogbo apoti esi idibo naa lọ pata. Bo si tilẹ jẹ pe ni Eko naa, ọpọlọpọ  awọn ile idibo ni awọn to n fi ẹhonu han bajẹ, ti wọn ni ko ni i si idibo nibẹ, sibẹ, awọn ti wọn ba jẹ ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, tabi awọn ti wọn ba ni ajọṣe pọ pẹlu wọn ni wọn n sọ pe ki wọn wọle idibo ni gbogbo agbegbe.

Ni ti ọkan pataki ninu ẹgbẹ NCNC to di ẹgbẹ UPGA, Adeniran Ogunsanya, yẹyẹ loun n fi awọn eeyan naa ṣe. Awọn ẹgbẹ Dẹmọ ti ro pe ko si wahala bo ba wọle, pe yoo pada waa ṣe tawọn ni. Loootọ nigba ti wọn si dibo, bo tilẹ jẹ ọkunrin naa ti ni oun ko ni i kopa ninu ibo ọhun nitori aṣaaju UPGA loun, sibẹ, oun naa lo wọle, to si fẹyin ọkunrin kan to duro fun ẹgbẹ NNA, T. A. Ọdẹniyi, janlẹ ni gbangba. Ibo ti wọn di fun Ogunsanya lai si nile ẹ yii din diẹ ni ẹgbẹrun meji ni, bẹẹ ni eyi ti wọn di fun Ọdẹniyi to wa nibẹ loju ẹ le diẹ ni ọgọrun-un meji. Ṣugbọn ni gbara to wọle, ti wọn si ti kede pe oun lo wọle lo ti kọwe lẹsẹkẹsẹ fi ipo rẹ silẹ, pe oun ko ṣe asọfin labẹ eto idibo bẹẹ, ki ẹgbẹ NPC tawọn Sardauna, ati awọn ẹka wọn ti wọn ti ko de ilẹ Yoruba maa ṣe ijọba naa lọ, awọn yoo jokoo lati wo ibi ti wọn yoo ba a ja.

Tai Solarin

Ija rẹpẹtẹ lo ṣẹlẹ kaakiri ni Ibadan, ọkan si le ti awọn ọlọpaa yinbọn lu ẹni kan, ti wọn si ṣe e leṣe taara. Bẹẹ ni awọn bii mẹjọ mi-in fara pa nigba ti ija ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ UPGA ati awọn Dẹmọ. Ariwo ‘a-o-dibo’ ni wọn n pa ni ọpọlọpọ agbegbe ni Ileṣa, ti wọn si ba ọpọ ile idibo jẹ pata. Ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Hausa, ko si wahala ẹyọ kan bayii nibi kan, wọọrọwọ ni wọn dibo wọn, bẹẹ ni ọpọ ero jade daadaa lati dibo. Nigba ti ibo naa n lọ lọwọ paapaa, Sardauna mu awọn minisita ijọba rẹ bii meji dani, wọn si jọ n yi awọn ilu nla ilẹ Hausa po, lati mọ ibi ti ohun kan tabi omi-in ba ti ṣẹlẹ, ṣugbọn ko si wahala kan fun wọn nibi kan. Ohun ti awọn aṣaaju wọn ti sọ fun wọn ni wọn tẹle, iba awọn oloṣelu to ba awọn UPGA ṣe ti wọn le fẹẹ fa wahala, wọn ti fi awọn ṣọja to n rin kiri laarin ilu, pẹlu ibọn ati lanrofa, se wọn mọle, ko sẹni kan to jade tabi waa pariwo kan nibi kan.

Pẹlu gbogbo aiṣedeede ti idibo naa mu dani l’Ekoo ati agbegbe rẹ, ni ọjọ keji ti wọn yoo ka ibo bayii, ijo lawọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ n jo, ariwo ayọ ni wọn si n yọ pe ẹgbẹ awọn ti wọle. Ni aarọ ọjọ keji idibo naa ni wọn ti sọ pe ẹgbẹ NNA, iyẹn ẹgbẹ NPC ti Sardauna ati NNDP, Dẹmọ ti Akintọla ti ni ọmọ ile-igbimọ aṣofin mẹrindinlọgọrin, nigba to jẹ mọkanlelogun pere ni awọn UPGA ni. Ohun to bi awọn ẹgbẹ UPGA ninu ree, ti wọn fi ni ohun ti awọn eeyan ri yẹn ki i ṣe idibo, iranu lasan, ẹtan ati fifi-tipatipa ṣejọba le awọn ọmọ Naijiria lori ni. Wọn ni ibo naa ko yatọ si ibo agbegbe ilẹ Hausa nikan, ko si si idi kan ti ẹnikẹni fi gbọdọ maa ṣe Naijiria lọ mọ, ki Aarẹ Nnamdi Azikiwe pe gbogbo awọn alaṣẹ ipinlẹ gbogbo jọ, ki wọn kuku jokoo, ki wọn si fọ Naijiria, ki onikaluku maa ba tirẹ lọ lai ni i ni wahala kankan. UPGA ni ẹtan ni ki awọn kan jokoo sibi kan ki wọn ni awọn n ṣe Naijiria, pe ijọba ilẹ Hausa nikan ni wọn n ṣe.

Dideolu Awolowo

Awọn Sardauna mọ pe iru ọrọ bayii le di wahala, wọn mọ pe bi ariwo naa ba pọ, kia ni awọn eeyan agbaye yoo da si  i. Nitori ẹ ni Mallam Muhammadu Ribadu ti i ṣe minisita fun eto aabo nilẹ wa nigba naa fi jade sọrọ, to ni ibo daadaa ni wọn di. O ni ṣebi wọn dibo ni ilẹ Hausa, wọn si di ni ilẹ Yoruba, ilẹ Ibo ti wọn ko ti dibo, ijọba UPGA lo sọ pe ki awọn eeyan ma jade, nigba ti ko si ti si awọn ti yoo ṣeto ibo, awọn to fẹẹ dibo ko jade. O ni ko si ohun to le mu Naijiria pinya mọ, nitori ijọba to dara ti fẹsẹ rinlẹ daadaa. Ṣugbọn gbogbo aye lo mọ pe ibo naa ko dara ṣaa, ohun ti wọn si n duro de bayii ni ọrọ ti yoo ti ẹnu aarẹ Naijiria igba naa, Ọlọla Nnamdi Azikiwe, jade. Yoo jẹ ki awọn araabi yii maa ṣejọba lọ ni, abi yoo takun di i fun wọn. Ohun tawọn eeyan fẹẹ mọ ni ọjọ kin-in, oṣu kin-in-ni, ọdun 1965 niyẹn.

Leave a Reply