Nigba ti yoo fi di ọjọ keji ti wọn dibo 1964 yii tan, awọn ijọba orilẹ-ede Naijiria ati awọn ẹgbẹ NPC labẹ Sardauna Ahmadu Bello ti wọn n ṣejọba naa ti mọ pe wahala gidi n bẹ fawọn. Wọn mọ pe ibo ti wọn di ti wọn n sọ pe awọn lawọn wọle yii yoo da rogbodiyan gidi silẹ, nitori ohun to n jade niluu ko daa, iroyin to si n jade lati ọdọ awọn orile-ede agbaye to ku naa ko bọ si i rara. Bi esi idibo ti n wọle lo n han pe o fẹrẹ ma si ibo ni ibomiiran ju ilẹ Hausa ati apa kan ilẹ Yoruba lọ. Lọootọ ni wọn dibo ni gbogbo ilẹ Hausa, ṣugbọn apa kan ni wọn ti dibo nilẹ Yoruba, nitori wọn ko tilẹ dibo l’Ekoo rara ni ka sọ. Ọna mẹrin ni wọn ti fẹẹ dibo lọ si ile aṣofin lati Eko, ọna kan ṣoṣo, nibi ti wọn ni wọn dibo fun TOS Benson nikan ni wọn ri gbe wọle, ibi ti wọn ni Adeniran Ogunsanya lo wọle ni Ikẹja, iyẹn loun ki i ṣe ara wọn, ki wọn ma forukọ oun si i.
Nibikibi ti wọn ba ti darukọ pe ọmọ ẹgbẹ UPGA kan lo wọle, bẹẹ lawọn yẹn n kọwe fi ipo ti wọn ni wọn yan wọn si naa silẹ, wọn yoo ni awọn ki i ṣe ọmọ ile-igbimọ aṣofin, bẹẹ ni ko sẹni to yan awọn si ile-igbimọ, ki ẹnikẹni ma darukọ awọn si i o, nitori o jọ pe awọn ti wọn n ṣeto idibo naa ti wọn n pe ni FEC, labẹ Ọgbẹni Esuam, ni wọn n ṣe ohun to wu wọn ni tiwọn.
Gbajumọ eeyan gbaa ni Babatunde Akin-Olugbade, ọkan pataki ninu ẹgbẹ AG ati UPGA ni. Ọjọ ti wọn yoo dibo gan-an lo de lati ilu oyinbo, sibẹ, nigba ti wọn dibo naa tan, wọn ni oun ni wọn da pada pe ko maa lọ sile-igbimọ aṣofin l’Ekoo lati adugbo wọn ni Abẹokuta. Ṣugbọn nigba ti wọn kede orukọ rẹ, ẹsẹkẹsẹ naa lo ti kede pe oun kọwe fi ipo ti wọn yan oun si naa silẹ, nitori oun ki i ṣe ara wọn rara. O ni gbọn-in loun wa ninu ẹgbẹ UPGA, oun si duro giri ninu ẹgbẹ ọhun, oun ko lọ sile-igbimọ aṣofin kankan o.
Ni ọjọ keji ti wọn dibo tan ni gbogbo eleyii ṣẹlẹ, ti esi idibo naa ko si ti i wọle tan, ṣugbọn o jọ pe o ti han bayii pe gbogbo ibi ti wọn ba ti ni UPGA wọle, awọn ti wọn ba darukọ ninu wọn yoo fi ipo naa silẹ ni, bẹẹ gbogbo ibi ti wọn ba ti le sọ pe ẹgbẹ NNA, iyẹn apapọ ẹgbẹ Dẹmọ ti Samuel Ladoke Akintọla ti i ṣe olori ijọba West, ati NPC, ẹgbẹ awon Sardauna, ti i ṣe olori ijọba ilẹ Hausa, lo wọle, bo jẹ ijokoo meji si mẹta, wọn gbọdọ fun awọn alatako wọn naa. Bi bẹẹ kọ, gbogbo aye ni yoo pariwo ole le wọn lori. Nigba to waa jẹ bi wọn ba ti darukọ UPGA nibi kan lawọn ti wọn ba ni wọn wọle n kọwe fipo silẹ yii nkọ o! Ọrọ naa gbe jẹbẹtẹ le wọn lọwọ, wọn ko si mọ ohun ti wọn yoo ṣe. Ohun ti awọn si ṣe n kọwe fipo silẹ ni ọrọ ti Muhammadu Ribadu, ọkan ninu awọn igbakeji ẹgbẹ NPC, to tun jẹ aṣaaju ninu NNA ti sọ. Ohun to sọ ni pe irọ ni UPGA n pa, wọn kopa ninu ibo naa, esi ibo to n wọle lo tu wọn fo.
Lati jẹ ki wọn mọ pe ko si UPGA to kopa ninu idibo ju awọn ti wọn jẹ aja ati ọmọlẹyin awọn Akintọla ati Sardauna lọ lawọn ti wọn ba darukọ ṣe n sare kọwe fipo silẹ, ko ma di pe wọn darukọ wọn si ohun ti ko dara. Nigba ti yoo fi di ọwọ ọsan ni ọjọ yii, awọn mọkanla ti wọn darukọ bẹẹ pe ọmọ UPGA to wọle sile aṣofin ti kọwe fipo naa silẹ, wọn lawọn ko ṣe o. Nigba ti nnkan yoo kuku tilẹ fọ loju pata, awọn mẹta ninu igbimọ to n ṣeto idibo yii kọwe fi ipo silẹ, wọn ni awọn ko le kopa ninu eto idibo naa mọ, tori awọn ohun to n ṣẹlẹ yii, ẹmi awọn ko gbe e rara. Itumọ eyi ni pe gbogbo ibo ti wọn di, ojooro ni. Awọn mẹta ti wọn kọwe fi ipo silẹ yii naa ni Ọgbẹni Anthony Aniagolu, olori awọn ti yoo ṣeto idibo ni gbogbo ilẹ Ibo; Ọgbẹni David Akenzua, olori awọn ti yoo ṣeto idibo ni gbogbo Mid-West ati Ẹni-ọwọ B. A. Adelaja, olori awọn ti yoo ṣeto idibo naa lagbegbe Eko.
Marun-un ni gbogbo awọn olori eleto idibo yii, ti ilẹ Ibo (East), ti ilẹ Yoruba (West), ti Mid-West, ti Eko (Lagos) ati ti ilẹ Hausa (North). Nigba tawọn mẹta ti waa kọwe fipo silẹ ninu wọn yii, ọrọ naa yoo le gan-an ni o, nitori ohun to tumọ si ni pe gbogbo ohun yoowu ti wọn ba kede, iyẹn esi idibo ti ajọ to ṣeto idibo yii, Federal Electoral Commisssion (FEC) ba lawọn kede, ko ṣeni ti yoo gba esi naa wọle, nigba ti awọn mẹta ninu marun-un ti lawọn ko lọwọ si i. Ohun to jẹ ki awọn NNA binu pe awọn kọmiṣanna eto idibo yii fi ipo wọn silẹ gan-an niyẹn. Wọn ni nitori kin ni, wọn ni awọn mọ ohun to ṣe wọn ti wọn fi kọwe fipo silẹ, pe ki i ṣe eto idibo ni ko daa, iṣẹ ti awọn egbẹ UPGA ran wọn ni wọn waa jẹ ni. Ẹgbẹ NNA yii, iyẹn ẹgbẹ Akintọla ati Sardauna, kọ ninu atẹjade ti wọn gbe sita lọjọ keji idibo yii pe awọn kọmiṣanna mẹtẹẹta ti mura lati da Naijiria ru pẹlu UPGA, ohun ti wọn ṣe kowe fipo silẹ niyẹn.
Ṣugbọn awọn UPGA naa ti gbọn, wọn ki i jẹ ki iru ọrọ bayii balẹ ti wọn yoo fi da si i. Lọjọ yii kan naa lawọn naa ti yaa sare gbe iwe jade, wọn ni awọn NNA n ṣaran lasan ni. UPGA ni ki lo kan awọn kan ileeṣẹ to n ṣeto idibo, pe iwa ifiniwọlẹ ati arifin gbaa lo jẹ si awọn eeyan gidi ti ijọba Naijiria ko jọ lati ṣeto idibo, ki wọn waa maa fẹsun kan wọn nitori wọn fi ipo silẹ, pe wọn ko ni ironu, tabi pe ẹni kan lo n ti wọn ti wọn fi ṣe ohun ti wọn ṣe. UPGA ni ṣebi gbogbo aye lo n woran pe ijọba Naijiria lo wa nidii gbogbo aburu ti eto idibo yii n mu wa yii, awọn NNA to jẹ ti ara ilẹ Hausa, ati awọn oponu eeyan ti wọn fẹẹ ta ogun ilẹ baba wọn ti wọn n lo nilẹ Yoruba ni wọn fẹẹ da orilẹ-ede naa ru pẹlu ojooro eto idibo, ki ijọba Naijiria le fi tipatipa wa lọwọ awọn Hausa yii ṣaa. UPGA ni ohun tawọn kọmiṣanna eto idibo yii ṣe, ki Naijiria le wa niṣọkan, ko si le duro giri ni, ki i ṣe fohun meji, tabi pe ẹni kan fun wọn lowo.
Nigba ti awọn naa ti ri i bi nnkan ṣe n lọ, gomina ilẹ Yoruba igba naa, Oloye Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi, sare gbe iwe jade fun gbogbo awọn ara Western Region, o ni ko si ohun to ku bayii lati ṣe ju ki wọn ṣe suuru gidi lọ o. O ni ki awọn oloṣelu gbogbo bu omi suuru mu, nitori ibo to waye ti waye, esi idibo naa si le le diẹ fun awọn mi-in lati gba a, ṣugbọn ki wọn gba a nitori ilọsiwaju Naijiria, ati alaafia ni ilẹ Yoruba. O ni bi awọn ba ti gba esi idibo naa wọle, wọn yoo tun ni aaye lati kopa ninu eto idibo mi-in lọjọ iwaju, pe eyi ti ko dara ni ki wọn ba nnkan jẹ lasiko yii, nitori wọn ko wọle, ki wọn ranti pe Naijiria yoo wa titi fun wọn lati kopa ninu eto idibo mi-in lọjọ iwaju o. Ṣugbọn awọn eeyan gbọ ọrọ baba yii ni, wọn ko gba a gbọ, koda, awọn mi-in ko feti si i, wọn ni kin ni yoo wi, ṣebi Akintọla lo gbe e sipo, kin ni yoo pada sọ!
Bi oun ti sọrọ naa ni gomina ilẹ Hausa, Alaaji Kashim Ibrahim, naa sọ ọ. Oun naa ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii, ki awọn oloṣelu ṣaa ti gba pe amuwa Ọlọrun ni. O ni o ti ṣẹlẹ, o ti ṣẹlẹ na, ibo ti waye ibo si ti lọ, ki wọn fara wọn mọra, ki wọn si maa ṣejọba lọ, ko ma di pe Naijiria to ṣẹṣẹ gba ominira yii yoo tun wogba mọ wọn lori.
Wọn loun naa ko ni ọrọ gidi kan ti yoo sọ lẹnu, pe ṣebi Sardauna lo yan an sipo rẹ, ọpọ anfaani loun naa si n jẹ ninu ijọba tawọn Hausa n ṣe yii, ki waa ni yoo ni ohun to ṣẹlẹ ko dara si. Awọn oloṣẹlu UPGA ni ohun to ṣẹlẹ ki i ṣe amuwa Ọlọrun, amuwa Sardauna pẹlu Akintọla ni, awọn ko si ni i gba fun wọn. Wọn ni ko si kinni kan ti ẹni kan le ṣe si ọrọ yii, afi ki wọn dajọ ibo mi-in kia, ki wọn si ṣe gbogbo eto to yẹ lati ri i pe ko si ojooro ati iwa ole buruku ti awọn NNA at iijọba Balewa ṣe kọja yii.
Ni ọjọ keji ti wọn dibo tan, iyẹn ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 1965, ni gbogbo eleyii n ṣẹlẹ ni Naijiria, ko si jọ pe ọdun naa yoo mu eeso rere kan wa, nitori ko sẹni to mọ ibi tọrọ naa yoo yọri si rara o. Gbogbo agbaye n reti Azikiwe, wọn n reti ohun ti yoo wi, nigba to jẹ gbogbo ibo ti wọn di yii, oun naa ni yoo pe ẹni ti yoo ṣejọba ko waa ṣe e, bi ko ba pe ẹnikẹni, ko si ohun ti wọn yoo le ṣe. Ṣugbọn ko jọ pe Azikiwe yoo raaye pe Balewa, nitori ariwo to n lọ lẹyin ibo yii ko daa.
Ẹ ka a siwaju si i lọsẹ to n bọ.