Ohun to fa wahala lasiko ibo ti wọn di ni 1964 niyi o (6)

Nigba ti yoo fi to bii aago mẹwaa aabọ ni ọjo kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 1965, ajọ to n ṣeto ibo ni Naijiria nigba naa, FEC, kede pe ẹgbẹ NNA ti wọle ibo ti wọn di ni ọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun 1964, ati pe wiwọle naa ko ni ariyanjiyan ninu, wọn wọle gedegbe ni.  Egbẹ NNA (Nigerian National Alliance) yii ni ẹgbẹ alajọṣepọ laarin ẹgbẹ NPC ti Sardauna Ahmadu Bello jẹ olori rẹ, ati NNDP (Egbẹ Dẹmọ) ti Akintọla n ṣe olori wọn. Wọn ni awọn ni wọn wọle ibo yii, wọn fi ẹyin alatako wọn, UPGA (United People’s Grand Alliance) gbolẹ. UPGA yii naa si ree, ẹgbẹ alajọṣepọ Action Group ati NCNC ni. Alaga eto idibo naa funra rẹ, Ọgbẹni Eyo Esua lo kede bẹẹ pe awọn NNA lo bori, o si ni ki gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu ti ọrọ naa ko tẹ lọrun gba ile-ẹjọ lọ. Ṣugbọn ko sẹni to da a lohun, nitori ko sẹni to mura lati lọ si ile-ẹjọ kankan.

Ẹgbẹ UPGA ti ni awọn ko kopa ninu idibo naa tẹlẹ, wọn lawọn ko si ninu ẹ, ki ẹnikẹni ma darukọ awọn si i. Ibi ti wahala wa ree, nitori yoo ṣoro ki ẹgbẹ NNA nikan too maa da ṣejọba. Ohun ti wọn ṣe ni awọn ni wọn wọle ni pe ninu ibo ijokoo mẹtadinlaaadọsan-an (167) ti wọn ti di nilẹ Hausa, NNA lo wọle, wọn ni wọn ti mu ijokoo ọgọjọ (160), UPGA si mu mẹta pere, awọn si n reti eyi to ku ti yoo jẹ ti awọn ninu NNA. Idaniloju yii wa nigba to jẹ ilẹ Hausa yii ni orirun ẹgbẹ naa, ibẹ ni Sardauna ti n ṣejọba. Ibo mẹtadinlọgọta (57) ni wọn n reti ni Western Region, ẹgbẹ Akintọla, NNA, yii ni awọn ti ko ijokoo ọgbọn (30), UPGA ni mọkanla, mẹrindinlogun to si ku yoo pada jẹ ti awọn ninu Dẹmọ. Bayii ni wọn pin nnkan naa mọ ara wọn lọwọ, to jẹ bi wọn ba da esi idibo naa silẹ loootọ, NNA, ẹgbẹ Sardauna, pẹlu Akintọla lo wọle.

Lọrọ kan, ajọ to ṣeto idibo ni awọn ti ṣa gbogbo esi jọ, NNA lo wọle, ki olori Naijiria, Nnamdi Azikiwe, tete pe ẹgbẹ NNA yii ki wọn waa bẹrẹ si i ṣejọba wọn. Ṣe ohun ti ofin sọ niyi, nigba ti ẹgbẹ oṣelu kan ba ti wọle, olori Naijiria ti wọn n pe ni purẹsidẹnti yoo pe iru ẹgbẹ oṣelu bẹẹ, yoo si fun un niwee aṣẹ lati lọọ bẹrẹ ijọba rẹ tuntun. Ohun ti wọn fẹ ki Azikiwe ṣe ree, ṣugbọn iyẹn ko da wọn lohun, o ni awọn ẹri wa dajudaju to fi han pe wọn ko dibo ni awọn ibi kan, ati pe awọn ẹgbẹ oṣelu to yẹ ko kopa ninu idibo naa ko kopa ninu ẹ. UPGA ni Azikiwe n sọ pe ko kopa, bẹẹ ilẹ Ibo naa lo n sọ pe wọn ko ti dibo. Ootọ si leleyii, ohun ti Sardauna, Balewa, Akintọla ati awọn aṣaaju ẹgbẹ NNA to ku mọ ni. Ṣugbọn wọn ko fẹẹ gba, wọn ni awọn ti wọle, awọn ti wọle na, ki Azikiwe pe Balewa pe ko maa ba ijọba rẹ lọ. Azikiwe ko da wọn lohun ṣaa.

Tafawa Balewa

Nibi ni ọrọ ti di iwaju ko ṣee lọ, ẹyin ko ṣee pada si, orilẹ-ede Naijiria si wa loju kan latigba naa lọ. Ko si ijọba ni Naijiria, nitori olori Naijiria ko pe ẹgbẹ oṣelu ti wọn sọ pe o wọle lati waa ṣejọba. Nigba ti ọrọ ti da bayii, Balewa funra rẹ gbera, ni bii aago mọkanla aabọ lọwọ iyalẹta, o lọ si ile aarẹ, o lọọ ba Azikiwe ṣepade, o ni awọn ti pari ibo, ko jẹ ki oun maa waa ṣejọba oun lọ. Azikiwe ni ko si ohun to jọ ọ, Azikiwe ni oun ko ni igbagbọ pe ibo kankan waye lọjọ naa, o si ko iwe oriṣiiriṣii kalẹ niwaju rẹ, ati iwe tawọn ẹgbẹ UPGA fi ni awọn ko ni i kopa ninu idibo naa, ati ti awọn adari ajọ eleto idibo ti wọn kọwe fi ipo wọn silẹ, ati ti ọpọ eeyan ti ko kopa ninu idibo naa rara. Gbogbo iwe yii lo fi han Balewa, to si sọ pe pẹlu iru awọn nnkan wọnyi, o ṣoro pupọ foun lati pe e pe ko maa waa ṣejọba rẹ lọ.

Ọrọ ti waa de oju rẹ bayii, Balewa ba ironu pada si ọọfiisi rẹ, nitori ohun ti yoo ṣe ko ye e mọ. Kia lo ti sọ fun Ribadu pe ko yaa gbe ẹronpileeni oun, ko tete lọọ ba Sardauna ni Kaduna, ko sọ bi ọrọ ti n lọ fun un. Lẹsẹkẹsẹ ni Ribadu gba Kaduna lọ. N loun funra rẹ ba pada si ọọfiisi rẹ, o n reti ohun ti yoo ṣẹlẹ. O sare pe awọn olori ogun lẹẹkan si i, olori ṣọja ati olori ọlọpaa pẹlu olori awọn ọmọ ogun oju omi ati ti ofurufu, awọn merẹẹrin si lọọ ri i. Lẹyin ti wọn ṣepade tan, ti awọn mẹrẹẹrin kuro, awọn ogunlọgọ ṣọja rọ de ile ijọba, ni ọọfiisi Balewa, ni Onikan, wọn si rọgba yi ile naa ka, wọn jokoo kaakiri goo goo goo pẹlu ibọn wọn. Bẹẹ naa ni wọn si ṣe ni ile olori ijọba yii naa, wọn ko ọlọpaa ati ṣọja sibẹ lati ri i pe ko si kinni kan to ṣẹlẹ si Balewa, boya ninu ile rẹ ni o tabi ni ọọfiisi rẹ nilẹ ijọba.

Bi awọn ṣọja yii ti n de, bẹẹ ni Ladoke Akintọla ti i ṣe olori ijọba Western Region de pẹlu ero lẹyin rẹ. Nigba to n bọ, o mu Fani-Kayọde ti i ṣe igbakeji rẹ lọwọ, Ọba Akran naa si tẹle wọn. Awọn yii wọle taara, wọn si jokoo ti Balewa titi. Ohun to daju ni pe Akintọla lọ lati fi i lọkan balẹ ni, ati lati sọ pe ko si kinni kan ti Azikiwe yoo ṣe fun un, nitori amofin lawọn, awọn si mọ ohun ti ofin sọ. Ni ọjọ yii kan naa, Balewa gbe iwe jade, o fi tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ. O ni oun ko fẹ ki itajẹsilẹ waye ni Naijiria nitori ọrọ ibo tabi ọrọ ijọba, bi ko ba fẹẹ ṣee ṣe, ki aarẹ Azikiwe pe ipade awọn olori ijọba ati aṣoju, ki wọn jọ jokoo lori bi wọn yoo ti ṣejọba Naijiria si, ki awọn si mọ ohun ti awọn yoo ṣe. O ni gbogbo ohun to fa ija yii ko ju pe Azikiwe ni ki oun sun ọjọ idibo siwaju, oun si sọ fun un pe ki i ṣe ojuṣe toun gẹgẹ bii olori ijọba, bẹẹ ni ki i ṣe ojuṣe tirẹ naa gẹgẹ bii olori Naijiria lati sun ọjọ idibo siwaju, ojuṣe awọn ti wọn n ṣeto idibo ni.

Balewa ni oun ti sọ fun aarẹ Azikiwe tẹlẹ pe ko ma da si ọrọ idibo yii, pe gbogbo awọn ti wọn n pariwo pe wahala idibo wa, tabi pe ojooro wa nibẹ, ile-ẹjọ oriṣiiriṣii lo wa ti wọn le lọ, awọn adajọ si wa nibẹ ti yoo laja, ti wọn yoo dajọ sibi to ba yẹ. O ni lẹyin ti oun ati Azikiwe ti jọ yanju ọrọ tan, tawọn tun ṣepade, lẹyin naa ni Azikiwe tun pada ni oun o ni i da si ọrọ idibo yii, o ni oun fẹ ki gbogbo ọmọ Naijiria mọ pe ohun to fa wahala naa niyẹn. Ṣugbọn ọtọ ni ohun ti Azikiwe n wi ni tirẹ, nitori oun naa kọwe tirẹ jade to si ni oun yoo fi ipo oun silẹ gẹgẹ bii aarẹ, ki awọn Balewa maa ṣejọba naa lọ funra wọn. Lọjọ kẹta ibo yii ni oun naa gbe iwe tirẹ jade, o ni oun fẹẹ sọ fun gbogbo ọmọ Naijiria pe oun ko le laju silẹ ki ofin ati eto iṣelu Naijiria toju oun bajẹ, bi ko ba kuku ṣee ṣe, ki oun kọwe fipo oun silẹ, ki awọn ti wọn ba fẹẹ ṣejọba si maa ṣejọba wọn lọ.

O ni ibo ti wọn n pariwo ẹ pe wọn di yii ki i ṣe ibo, ko si ibo nibẹ rara, oun ko si le tori eyi pe ẹni kan ko maa waa ṣejọba lọ. O ni bi Balewa ba mọ pe oun fẹẹ ṣejọba, ti wọn si fẹ ki oun lọwọ si i, a jẹ pe wọn yoo pa ibo ti wọn di kọja naa rẹ, wọn yoo si tun ibo mi-in di, eyi nikan ni oun le fọwọ si. Bayii ni ọjọ kin-in-ni lọ, ti ọjọ keji naa tun lọ, ti ọrọ naa ko si ti i yanju. Ṣe Azikiwe yoo kọwe fi ipo rẹ silẹ ni, tabi Balewa ni yoo gbejọba silẹ fun ẹlomiiran. Tabi wọn yoo yan ijọba fidi-hẹ-ẹ lati maa ṣejọba lọ titi ti wọn yoo fi le ṣeto idibo mi-in ni. Ẹnu ibeere yii lawọn eeyan wa titi di ọjọ kẹrin ti wọn dibo tan, awuyewuye to si gba igboro kan ni pe Azikiwe n lọ, o ti fẹẹ ko ẹru rẹ kuro nile ijọba. Ṣugbọn bi Azikiwe ba lọ, kin ni yoo ṣẹlẹ si Balewa. Ohun tawọn eeyan ko ti i mọ idahun si titi di ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun 1965, niyi o.

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply