Ohun to fa wahala lasiko ibo ti wọn di ni 1964 niyi o (Ipari)

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni ile-ẹkọ giga gbogbo ti pariwo sita pe ki awọn ti wọn n ṣejọba Naijiria ma jẹ ki ohun to n ṣẹlẹ lẹyin idibo ti wọn di yii da ogun silẹ, nitori ọrọ naa ti di ohun tẹnikẹni ko le sọ ibi ti yoo pada ja si mọ. Ẹgbẹ awọn akẹkọọ yii, National Union of Nigerian Students gbe iwe jade, wọn ni ko si ohun to yẹ ki ijọba ṣe ju ki wọn gbe igbimọ ti yoo ṣejọba fidi-hẹẹ jade, ki awọn eeyan ti wọn ba yan sibẹ ṣejọba fun oṣu mẹfa, ki wọn ṣeto ibo tuntun, ki wọn si gbe ijọba fun awọn ti wọn ba wọle. Awọn akẹkọọ yunifasiti gbogbo yii ni ibo ti wọn di ni ọgbọn ọjọ oṣu kejila ọdun 1964 yii ki i ṣe ibo to ṣee gbe ẹnikẹni wọle gẹgẹ bii olori ijọba Naijiria, tabi gẹgẹ bii awọn aṣofin, nitori ibo apa kan lasan ni, ẹyẹ ko si le fi apa kan fo. Wọn ni ki olori Naijiria funra rẹ, Ọlọla Nnamdi Azikiwe, bẹrẹ eto kia, ko ko awọn gomina ipinlẹ gbogbo jọ, ki wọn si jọ ṣeto ijọba fidi-hẹẹ yii.

Awọn oloṣelu ko fẹẹ gbọ bẹẹ ṣaa, nitori iwe ti Azikiwe kọ sita, ati eyi ti Balewa kọ jade, wọn ko jẹ ki wọn sọrọ naa sita, awọn eeyan gba iwe naa pada lọwọ wọn, wọn ni ki wọn ko o sọwọ pada, ki awọn wa ọna mi-in lati yanju ọrọ yii. Eyi ni pe iwe ti Azikiwe kọ pe oun yoo fi ijọba silẹ, ti oun ko ni i ba wọn ṣe mọ, nitori oun ko le pe Tafawa Balewa pe ko waa ma ṣejọba lọ, nigba ti oun mọ pe ibo ti wọn di ko daa, iwe naa ko ṣiṣẹ mọ, nitori wọn ni ko mu un dani, ko le fi ijọba silẹ bẹẹ, ko jẹki awọn yanju ọrọ naa. Bakan naa ni eyi ti Balewa kọ to fi sọrọ lile, wọn ni ki oun naa gba iwe naa pada, nitori ọrọ inu ẹ ti le ju, nigba ti o ti sọ pe bi Azikiwe ba fẹẹ fi ijọba silẹ ko maa lọ, ẹlomi-in yoo ṣe e. Balewa ti kọwe, o si jọ pe o ti yọnda fun Azikiwe ko fi ijọba silẹ bo ba fẹẹ fi i silẹ, nitori oun ro pe ọpọ n gbe lẹyin awọn eeyan ẹ ti wọn jẹ Ibo ni.

Amọ gbogbo ọrọ naa ko ti i niyanju, nitori Azikiwe sa ni oun ko gba, ohun ti oun ṣe ni lati tẹ le ofin. Lasiko yii, gbogbo ohun ti Ọbafẹmi Awolọwọ ti pariwo rẹ fun ọkunrin olori NCNC naa latijọ ṣẹṣẹ waa ye e, iyẹn naa si ni iwa awọn oloṣelu lati ilẹ Hausa. Bakan naa awọn oloṣelu ilẹ Ibo duro lẹyin oun naa gbagbaagba, wọn ni ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ, bo ba fi le fijọba silẹ, Naijiria yoo daru ni, nitori ko si ẹni ti yoo jẹ ki Balewa naa maa ṣejọba lọ. Ọmọleewe kan tilẹ wa to n jẹ Isaac Boro, oun lo pada fẹẹ fibọn gbajọba ni Naija-Delta ni 1968, ṣugbọn ni asiko rogbodiyan Azikiwe ati Balewa yii, ọmọleewe ni, oun ni olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni yunifasiti Naijiria, iyẹn University of Nigeria, to wa ni Nzuka. Nigba ti ọrọ naa le tan, oun pe awọn ẹgbẹ akẹkọọ rẹ jọ, wọn si gba ile-ẹjọ lọ, wọn ni ki adajọ yọ Balewa nipo olori ijọba Naijiria kiakia.

Loootọ Ọgbẹni Isaac Boro ati Jude Emezie ni wọn pe ẹjọ yii, ṣugbọn orukọ awọn ọmọ ileewe yunifasiti Nzuka ni wọn fi pe e , eyi si jẹ ki ọrọ naa rinlẹ ju bo ti yẹ lọ, ariwo ọrọ naa si gbilẹ, wọn ni wọn fẹẹ yọ Balewa nijọba. Boya ọrọ naa iba ma ti le to bẹẹ ti ki i ba ṣe ilẹ Ibo ni Nzuka, awọn ti wọn si pẹjọ yii naa, Ibo ni wọn ka wọn si. Loju awọn Balewa ati Alaaji Ahmadu Bello ti i ṣe Sardauna, gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, iṣẹ ọwọ Azikiwe ni, nigba to jẹ oun ni olori awọn Ibo, to si jẹ awọn Ibo nikan ni wọn n pariwo pe ibo ti wọn di naa ko dara, nitori wọn ko kopa ninu rẹ, Michael Okpara ti i ṣe olori ijọba agbegbe naa, to si tun jẹ olori UPGA, ni ko jẹ ki wọn kopa nibẹ. Ohun ti awọn Sardauna ati Balewa n gbe kiri ree, wọn si sọ ija naa di ija laarin awọn Hausa ati Ibo. Eleyii jẹ ki ọrọ naa tubọ fọ loju.

Ladoke Akintola

Ijọba ẹgbẹ Dẹmọ to wa nilẹ Yoruba naa ko mu ọrọ ọhun rọrun, gbogbo ọna ni wọn wa lati mu nnkan le fun Azikiwe ati awọn Ibo to ku. Niwọn igba to ti jẹ alajọṣepọ ni ẹgbẹ Dẹmọ ati ẹgbẹ NPC tawọn Sardauna, bi ẹnikẹni ba doju ija kọ Hausa tabi ẹgbẹ NPC, awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ti olori wọn jẹ Oloye Ladoke Akintọla ti i ṣe olori ijọba Western Region yoo foju onitọhun ri mabo, awọn ni wọn wa ni gbogbo Guusu ilẹ Naijiria ti wọn n gbeja awọn ara Ariwa. Awọn naa ko fẹran Azikiwe, nitori wọn ri i bi ọta fun awọn naa, pe oun ni ko fẹẹ jẹ ki awọn de ibi ti awọn n lọ. Ṣe bi wọn ba wọle ibo, ti NNA, ẹgbẹ alajọṣe pọ yii ba fi le gbajọba, awọn Akintọla ati Sardauna ni wọn yoo jọ maa ṣejọba naa, ẹgbẹ Dẹmọ yoo ri ọwọ mu, yoo si di ẹgbẹ to lẹnu rẹpẹtẹ ninu ijọba apapọ, ko si sẹni ti yoo lagbara to wọn nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo.

Eyi lo si fa a to jẹ bi awọn ti wọn jẹ majẹ-o-bajẹ ti n wa ọna ẹrọ lati yanju ọrọ naa, awọn Sardauna ati Akintọla nigbagbọ pe ọwọ lile lo ṣee mu Azikiwe, pe ti wọn ba fi ọwọ lile mu un, yoo si sọrẹnda, wọn yoo gbe e kuro nile ijọba pẹlu itiju ni. Ohun ti awọn mura lati ṣe fun Azikiwe ko daa. Awọn Akintọla ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Yoruba ti wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ, nidi eyi ni wọn ti fi Sardauna lọkan balẹ pe awọn yoo mọ ibi ti awọn yoo ti mu un. Ohun ti Sardauna yoo ṣe ni tirẹ ko ju ko jẹ ki awọn ologun Naijiria ti ṣee ti lọ. Wọn ni ki Sadauna ri i pe awọn ọmọ ologun gbogbo, paapaa awọn ṣọja ti gbaradi, bi ọrọ naa ba fẹẹ di wahala, ki wọn le ko awọn ti wọn ba wa nidi ẹ lọ rau. Ni ti awọn Akintọla nti wọn n fẹẹ lo awọn akọṣẹmọṣẹ, ohun ti wọn yoo ṣe fun Azikiwe ko gba wahala rara, bii ọmọde meji n ṣere ni.

Wọn yoo ka Azikiwe mọ inu ile rẹ, wọn yoo si fi tipa mu un lọ si ọsibitu ni, tabi ki wọn ti i mọ inu ile rẹ, ki wọn ri i pe o ko le ba ẹnikẹni sọrọ, ẹnikẹni ko si ri i. Nigba naa ni wọn yoo sọ fun gbogbo aye pe o ti n ṣe gán-án gàn-àn gán, ori rẹ ti yi, ko mọ ohun to n ṣe mọ. Ohun ti wọn yoo ṣe ṣe bẹẹ ni pe ọna kan naa ti wọn fi le yọ olori Naijiria kuro nipo rẹ ree, afi to ba tun ku. Nigba ti wọn ko si fẹẹ ni oku eeyan lọrun, wọn ko ro iku ro o, wọn kan fẹẹ pa saye ki wọn si gba ijọba naa kuro lọwọ rẹ ni. Eto ti awọn n ṣe niyi, awọn Akintọla ati awọn ọmọ Yoruba mi-in ti wọn jẹ oniṣegun oyinbo, ati awọn agbẹjọro ni wọn jọ n ṣe ọrọ naa ni ọrọ awo, ọpọ eeyan ko si mọ si i rara, ohun ti wọn n reti ni ki wọn bẹ Azikiwe ko ma gbọ, ko sa maa ṣe agidi rẹ lọ, nigba naa ni wọn yoo jade si i lojiji, ko si too mọ bi yoo ti jẹ, ọrọ naa yoo ti mu un lomi.

Ọrọ naa ta si Azikiwe leti, ṣe bi awo ṣe n lu ni awo n jo, awọn Ibo ẹgbẹ rẹ ti wọn jẹ awọn ti wọn sun mọ awọn Yoruba oloṣelu gbọ kinni naa, wọn si ni ko ṣọra, bii bẹẹ kọ, ohun ti wọn fẹẹ ṣe fu un ko daa. Ni paapaa julọ, awọn olori ologun gbogbo ko yee paara ile Tafawa Balewa, wọn ko si de ọdọ Azikiwe rara, oun naa si mọ pe eleyi lewu foun. Bakan naa, awọn ṣọja ti yi ile oun naa po, wọn ni wọn n ṣọ ọ ni, bẹẹ ni ki i ṣe pe oun lo beere pe ki awọn ṣọja waa ṣọ oun, o kan ri wọn lojiji ni. Awọn Balewa ni ki wọn le waa daabobo o nitori wahala to n lọ yii ni, ṣugbọn oun naa mọ pe ki i ṣe idaabobo kan ni wọn ba wa, wọn fẹẹ mu oun bi ọrọ naa ba le ju bẹẹ lọ ni. Pẹlu gbogbo eleyii, ti Azikiwe funra ẹ si ri i pe awọn eeyan yii ti yi oun po, ti oun ko ni ọna ti oun le ba yọ lọwọ wọn, o ju ọwọ silẹ, nigba ti wọn si pada wa pe ki wọn yanju ọrọ naa, o ni oun ti gbọ, o si ti gba si wọn lẹnu.

Bẹẹ ni ọrọ ibo naa pari, Azikiwe si fi agbara tipatipa pe Tafawa Balewa ko wa maa ba ijọba rẹ lọ. Ni ọsẹ kan leyin ti wọn ti dibo ni eyi ṣẹlẹ, ọrọ naa si jẹ nnkan ibanujẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria kari-kari.

Leave a Reply