Ohun to mu PDP ati Eyitayọ Jẹgẹdẹ fidirẹmi l’Ondo gan-an niyi

Aderounmu Kazeem

Bo tilẹ jẹ pe eto idibo oṣelu ti waye l’Ondo, ti ẹnikan si ti jawe olubori, idi ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ, oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fidi rẹmi ti n foju han bayii.

Ibo to waye lọjọ Satide, Abamẹta yii ni igba keji ti Jẹgẹdẹ yoo jade lati dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. Ẹẹmejeeji ọhun lo si ti jabọ, bẹẹ lo jẹ pe Rotimi Akeredolu kan yii naa lo la a mọlẹ nigba mejeeji ọhun.

Dokita Kayọde Ajulọ, alaga tẹlẹ fun bọọdu to n mojuto ileeṣẹ Radio-Vision l’Ondo ti sọ pe wahala to wa ninu ẹgbẹ PDP l’Ondo gan-an lo da nnkan ru mọ Jegẹdẹ lọwọ, ati pe, ọga e nigba kan, Oluṣegun Mimiko paapaa ko mu un ni kekere pẹlu ẹ, niṣe ni wọn tẹle e gidigidi.

O ni, ọkunrin naa lanfaani nla lati jawe olubori ninu ibo to lọ yii, kani o lo ọgbọn ti Akreedolu lo ni, to si yanju wahala to ni pẹlu awọn kan nidii oṣelu.

Ajulọ sọ pe, ni kete to ti kuna lati yanju wahala to wa laarin oun ati Oluṣẹgun Mimiko, ti wahala inu ẹgbẹ PDP naa ko si kuro nibẹ, o ni iyẹn gan an ni gbongbo ohun to fa ijakulẹ ẹgbẹ naa lọjọ Satide to kọja yii.

Ṣe lasiko ijọba Mimiko l’Ondo, Eyitayọ Jẹgẹdẹ yii ni Olootu eto idajọ nipinle naa, ati pe oun gan-an ni Mimiko fa kalẹ gẹge bii ẹni ti yoo gba ipo e, ṣugbọn nigba tọrọ di ibi ka nawo, wọn ni, nibẹ gan-an ni Mimiko ti ja a kulẹ,  tọrọ ọhun si da ikunsinu silẹ laarin wọn lọdun 2016, bi PDP ṣe kuna niyẹn ninu ibo ọhun.

Nigba to di ọdun 2020 yii ti Jẹgẹde tun jade, Mimiko to ti gba inu ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party lọ ko lẹni meji to tẹle ju Ajayi Agboọla lọ, bo tilẹ jẹ Jẹgẹdẹ wa a lọ sile lati yanju wahala aarin wọn.

ALAROYE gbọ pe, nibẹ ni wahala yẹn ti kọkọ bẹrẹ, nigba to tun dijọ ti wọn n ṣe aṣekagba ipolongo ibo wọn, niṣe lawọn agbagba ẹgbẹ ti wọn wa si Ondo paapaa fi ẹgbẹ oṣelu ọhun han gẹgẹ bii ile ti wahala gidi wa ninu ẹ pẹlu bi awọn kan ṣe ṣi fila lori Fayoṣe ti ọrọ naa si dariwo rẹpẹtẹ.

Ajulọ sọ pe, ohun to ba Akeredolu ṣe e ni bo ti ṣe yanju wahala to ni pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ APC, nibi to ti bẹ gbogbo awọn to ti ṣẹ, ti gbogbo wọn si fọwọ wọnu lati ṣiṣẹ fun ẹgbẹ. O ni, eyi gan an lo mu ọkunrin naa jawe olubori lẹẹkan si i l’Ondo.

 

Leave a Reply