Ohunkohun ko ni i ṣe Sunday Igboho-Kunle Ọlajide

Faith Adebọla

Ọkan pataki ninu awọn aṣaaju ilẹ Yoruba, Dokita Kunle Ọlajide, ti sọ pe ko si ohun kan to le ti ki i rọ, ati pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ lọwọ si Sunday Igboho yii, gbogbo rẹ yoo di ohun itan. Bẹẹ lo ni awọn nigbagbọ pe kinni kan ko ni i ṣe Sunday Igboho.

Akọwe Ẹgbẹ Igbimọ Agba yii sọ eyi di mimọ lasiko to n ba ALAROYE sọrọ lori bi awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣe mu ọkunrin ajijagbara yii ni Orileede Olominira Benin, lasiko to fẹẹ kuro ni orileede naa.

Baba yii ni ‘A dupẹ pe Sunday Igboho ṣi wa laye ati laaye,  Ọlọrun ko fi ẹmi ẹnikẹni le eeyan kankan lọwọ. Ti ijọba ba gba pe Sunday Igboho ṣẹ sofin, ki wọn gbe e lọ si ile-ẹjọ, to ba de ile-ẹjọ, ti wọn ba ka ẹṣẹ  ti wọn ro pe o ṣẹ, oun naa lanfaani lati sọ pe oun jẹbi tabi oun ko jẹbi.

‘’Se ni ka kun fun adura gidigidi lori bi gbogbo nnkan ṣe ri lasiko yii. Ifọwọsowọpọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Naijiria ati Benin ni wọn fi mu ọkunrin naa. Ṣẹ ẹ mọ pe bi wọn ba ni wọn n wa eeyan, paapaa nilẹ Afrika yii, wọn yoo ranṣẹ si gbogbo awọn ọtẹlẹmuyẹ to wa ni awọn orileede mi-in kaakiri, ohun to fa bi wọn ṣe mu un niyi.

‘’Sugbọn labẹ bo ṣe wu ko ri, oju gbogbo agbaye lo n wo gbogbo ohun to n ṣẹlẹ. Ki Sunday Igboho si ma ba ọkan jẹ, ko nireti, ohun gbogbo yoo pada daa, a nigbagbọ pe ko si nnkan to maa ṣe e.’’

Leave a Reply