Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Titi di ba a ṣe n sọ yii, ha-in ni ọrọ iku ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa nni, Murphy Afọlabi, ṣi n jẹ fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ. Ohun to ṣe gbogbo awọn eeyan ni kayeefi lori ọrọ yii ni pe ki i ṣe pe o saisan, koda, oko ere kan ni wọn ni oṣere naa wa niluu Ọyọ to fi ṣubu, ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan fun itọju, ṣugbọn gbogbo igbiyanju awọn dokia lati doola ẹmi oṣere ọmọ bibi ilu Oṣogbo naa lo ja si pabo, akukọ kọ lẹyin ọmọkunrin. N ni iṣu ba dilẹ lẹyin asunsun-jẹ, aaro dilẹ lẹyin amukoko, Murphy ọmọ Afọlabi faye silẹ, o gbọrun lọ.
Iroyin meji ọtọọtọ lawọn ta a pe lori iṣẹlẹ naa sọ fun wa. Bawọn kan ṣe n sọ pe ilu Eko lo ku si, nile rẹ to wa ni Ikorodu. Wọn ni ileewẹ lo ti yọ ṣubu. Bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ilu Ọyọ ni oṣere na ti mi imi ikẹyin.
Ọkan ninu awọn oṣere ipinlẹ Ọyọ to ba wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo ohun laṣiiri sọ pe oko ere ni Murphy wa ti nnkan naa fi ki i giri, ti wọn si gbe e lọ sọsibitu, ṣugbọn ti oṣere yii ko pada ji saye mọ.
Ọpọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ ni wọn ti n daro iku to mu ọkan ninu wọn lọ yii, ti wọn si n kọ ọrọ aro loriṣiiriṣii.
Ohun to daju ni pe oṣere yii paapaa ko mọ pe iku naa yoo ya kankan bẹẹ, nitori ẹbẹ kan to n bẹ Ọlọrun lasiko to ṣe ayẹyẹ ọjọọbi rẹ lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni pe ki Ọlọrun ran oun lọwọ ki oun le sun mọ Ọn si i. Murphy kọ ọ bayii pe, ‘‘Si Iwọ Ọlọrun mi, lọjọ oni to jẹ ayajọ ọjọọbi mi yii, mo beere fun ibukun ati oore-ọfẹ Rẹ. Mo gbadura fun okun ati igboya lati tẹsiwaju ninu sinsin Ọ pẹlu otitọ. Ọlọrun Alagbara, mo wa sọdọ Rẹ lọjọ ayajọ ọjọọbi mi yii, mo si beere fun ojurere Rẹ. Mo gbadura pe ki o kun mi pẹlu ọgbọn ati imọ lati le ṣe ifẹ rẹ, ki n si le gbe igbe aye ododo. Mo ki ara mi ku ayẹyẹ ọjọọbi’’. Bi oṣere naa ṣe kọ awọn ọrọ yii sori ikanni rẹ niyi, ti ko si sẹni to mọ pe ọrọ idagbere tabi ọjọọbi ti yoo ṣe kẹyin loke eepẹ ree.
Awọn to sun mọ ọn sọ pe ọdun to n bọ lo n wo niwaju, to si ti ni in lọkan pe oun yoo ṣe ayẹyẹ ọjọọbi aadọta ọdun ti oun de oke eepẹ, lai mọ pe ọmọkunrin naa ko ni i pari oṣu Karun-un, ọdun yii.
Ọkan ninu awọn oṣere ti ọrọ iku Murphy Afọlabi tun ka lara ni oṣere ẹgbẹ ẹ kan, Kọlawọle Ajeyẹmi, ti i ṣe ọkọ Toyin Abraham. Ninu fidio kan ti oṣere naa gbe sori Instagraamu rẹ lati bu ọla fun Murphy Afọlabi, oṣere yii lo ti n ṣomi loju kikan kikan, to si gbe orin aro kan ti Tọpẹ Alabi kọ sabẹ idaro rẹ yii. Labẹ fidio naa lo kọ ọ si pe Murphy, o daarọ. Sunday to dudu batakun ni Sunday oni yii.
Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ ni Yọmi Fabiyi kọ ọ si pe, ‘Mo ṣi n wo itakurọsọ ti emi pẹlu rẹ ni gbẹyin, Murphy. O jẹ ẹni kan ti Ọlọrun fun ni ẹbun, o ni ọgbọn atinuda to pọ, o jẹ eeyan to tẹpa mọṣẹ daadaa, eeyan jẹẹjẹẹ to ni irẹlẹ ni ọ, o si maa n ṣatilẹyin fawon eeyan. Ṣe o waa tumọ si pe mi o ni i fi oju mi kan ọ mọ bayii, Ben 3, ṣe o di gbere naa nu un. Iba jẹ pe iku yii fun wa lanfaani lati sare sọtun-un sosi ka le du ẹmi rẹ ni, mi o ba ṣe gbogbo ohun to wa ni ikapa mi, mo si mọ pe o mọ eleyii.
O tun dun mi pe mi o ni i si nibẹ lati bu ọla ikẹyin fun ọ.
Nigba ti ALAROYE ṣabẹwo si ile mọlẹbi oloogbe naa to wa ni Fẹtuata, Isalẹ Ọṣun, niluu Oṣogbo, paroparo ni ibẹ da. Niṣe loju awọn to wa lagbegbe ibẹ le koko, ti ẹnikẹni ko si ṣetan lati ba akọroyin wa sọrọ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un yii, la gbọ pe wọn yoo gbe oku oṣere to kọ Iofa, to si mọ tifun-tẹdọ rẹ yii pada siluu Oṣogbo, ti wọn yoo si sin in si ile kan ti wọn ni oṣere naa n kọ lọwọ siluu ọhun bi ohun gbogbo ba lọ bi oṣere kan to ba wa sọrọ ṣe sọ.