Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ẹgbẹ PDP yoo yan oludije funpo gomina wọn l’Ọṣun 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lọwọlọwọ bayii, awọn aṣoju lati wọọdu idibo ojilelọọọdunrun o din mẹjọ (332) to wa nipinlẹ Ọṣun ti kora jọ pọ lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ naa ninu idije gomina ti yoo waye loṣu Keje, ọdun yii.

Ori papa iṣere ilu Oṣogbo nidibo naa yoo ti waye, oludije mẹfa ni wọn si ti jade lati dupo naa.

Awọn oludije naa ni Alhaji Akinade Akinbade, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, Sẹn. Ademọla Adeleke, Ọnarebu Sanya Omirin, Ọgbẹni Dele Adeleke ati Dokita Akin Ogunbiyi.

Ṣaaju ni wahala oriṣiiriṣii ti n fi ẹgbẹ naa logbologbo lori ẹni ti yoo jẹ alaga ẹgbẹ naa l’Ọṣun, bi awọn abala kan ṣe n tẹle Sunday Bisi ni awọn kan sọ pe Wale Ojo ni alaga tawọn.

Wahala yii lo yọri si bi idibo wọọdu wọn to waye l’Ọṣun loṣu to kọja fi mu itajẹsilẹ lọwọ, eleyii to yọri si iku eeyan meji niluu Ipetumodu ati ilu abule Agbẹrire, niluu Iwo.

Amọ ṣa, a ko ti i mọ boya idibo abẹle wọn loni-in yoo fopin si gbogbo wahala naa.

Leave a Reply