Ọjọ keji tawọn tẹnanti kan ko wọle ni wọn ji ọmọ mẹta gbe sa lọ l’Ajuwọn

Jọkẹ Amọri

Afi ki gbogbo awọn ti wọn maa n fi awọn ọmọ wọn silẹ fun awọn ti wọn ko mọ ri maa ṣọra ṣe pẹlu bi awọn eeyan ṣe n lo anfaani pe awọn obi gbẹkẹle wọn, wọn fi awọn ọmọ wọn silẹ fun wọn, ti wọn si n ji awọn ọmọ naa gbe sa lọ.

Iru iṣẹlẹ yii kan naa lo ṣẹlẹ ni Opopona Itsekiri, Ajuwọn, nipinlẹ Ogun, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji yii, gẹgẹ bii iwe iroyin ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni The Cable ṣe ṣalaye rẹ. Niṣe ni awọn tẹnanti meji ti wọn ṣẹṣẹ ko wọnu ile kan ji awọn ọmọ mẹta gbe sa lọ ninu ile naa lọjọ keji ti wọn ko debẹ.

Awọn obinrin meji kan ti ọjọ ori wọn wa laarin ọgbọn ọdun la gbọ pe wọn lọ si ile naa, ti wọn si ni awọn feẹ rẹnti ile. Wọn ni akẹkọọ ileewe kan niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lawọn, ọsẹ mẹta pere lawọn si  maa lo, nitori awọn ni idanwo kan tawọn fẹẹ ṣe lawọn ṣe fẹẹ gba ile naa, kawọn le duro sibẹ tawọn fi maa pari idanwo naa.

Bi wọn ṣe gba yara kan ọhun niyẹn. Ọjọ ti wọn ti dele naa ni wọn ti n ba awọn ọmọ to wa ninu ile ọhun ṣere, tawọn ti wọn jọ n gbe si ri wọn bii ẹni to ko eeyan mọra. Eyi lawọn obi awọn ọmọ yii ri ti wọn fi tura silẹ, ti wọn ko si ri ohun to buru ninu ere ti wọn n ba awọn ọmọ wọn ṣe.

Nigba to di ọjọ keji lawọn eeyan naa ba ni awọn fẹẹ lọọ ra nnkan nile itaja igbalode kan to wa ni adugbo naa. Ni wọn ba ko awọn ọmọ araale wọn mẹta naa dani lọ. Alọ awọn eeyan naa atawọn ọmọ yii ni wọn ri, wọn ko ri abọ wọn. Niṣe ni wọn ko awọn ọmọ naa lọ raurau.

Wọn ti fi iṣẹlẹ naa to wọn leti ni teṣan ajuwọn. Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹ̀ẹ naa mulẹ. O ni wọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn leti pe awọn obinrin naa waa gbale ni adugbo naa ni, lai mọ pe wọn ni ero buruku lọkan. O ni iwadii ti n lọ lati ri awọn oniṣẹẹbi naa mu.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii kan naa ni obinrin kan dibọn bii ẹni to fẹẹ maa kọ awọn ọmọ ni lẹsinni ni ipinlẹ Rivers, o tan baba ọkan ninu awọn ọmọ naa pe ko ba oun ra igi ti oun fi le kọ bii ahere ti yoo ti maa ṣe lẹsinni yii.

Iwe tawọn ọmọ naa yoo fi kọ nnkan si lo ni oun fẹẹ lọọ ra fun wọn to fi ko awọn ọmọ keekeeke marun-un lọ, ti wọn ko si ti i ri wọn di ba a ti n sọ yii.

 

Leave a Reply