Ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 2023, ni idibo aarẹ yoo waye nilẹ wa

 Olajide Kazeem

Ajọ eleto ilẹ wa, INEC, ti kede pe ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 2023, ni eto idibo aarẹ yoo waye kaakiri ilẹ Naijiria.

Alaga ajọ naa, ̀Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lo sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, niluu Abuja, lasiko to n ba awọn ọmọ ile-igbimọ aṣoju-sọfin sọrọ lori atunṣe iwe ofin ọdun 1999.

Ni kete ti ikede ọhun ti waye lawọn eeyan kan ti sọ pe gaga lara awọn oloṣelu kan yoo ti maa ya bayii, ti imura yoo si bẹrẹ lori eto ipolongo wọn lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC t’awọn Muhammed Buhari n dari.

Wọn ni bi awọn ẹgbẹ oṣelu alatako yoo ṣe bẹrẹ imura wọn, bẹẹ ni kinni ọhun ko ni i yọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC funra wọn silẹ, paapaa Aṣiwaju Bọla Tinubu. Wọn lo jọ pe o wu ọkunrin oloṣelu yii lati wa niluu Abuja, nibi ti yoo ti maa dari gbogbo ọmọ Naijiria ni kete ti Buhari ba ti pari saa ẹ nile ijọba.

Atiku Abubakar toun naa ti n wa kinni ọhun tipẹ naa ko gbẹyin o, ni bayii ti ikede ọjọ ti idibo sipo aarẹ yoo waye ti di mimọ, eto loriṣiiriṣii lawọn eeyan yii yoo maa ronu nipa ẹ, ti yoo si da bii ki ọjọ ọhun ti de gan-an.

One thought on “ Ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 2023, ni idibo aarẹ yoo waye nilẹ wa

  1. Ki Olorun Oba saanu fun awa omo Naijiira ni o, awon to ndari wa nilu yi ko ri ti awa mekunnu ro rara o, a nsoro bi orileede Naijiira yoo to da, awon nsoro idibo aare odun 2023.Imo tara eeni nikan londa awon olori ilu yi laamu. Emi tiko nii dola to ndapari osu.
    Afi ki awa omo Naijiira kun fun afura gidigidi ni orileede yi ni o, pe ki Olorun gba ijoba lowo awon to n niwa lara lorileede yi
    Asiko si ti to ti onikaluku yoo piya ni ilu yi
    Oodua Republic Must Stay And Stand

Leave a Reply