Ọjọ kẹta ti Emmanuel bẹrẹ iṣẹ lo gbe ọkada ti wọn gbe fun un sa lọ, Ogere lọwọ ti tẹ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ileeṣẹ kan to maa n lo ọkada lati fi ẹru jiṣẹ fawọn eeyan ṣẹṣẹ gba ọkunrin yii, Emmanuel Samuel, siṣẹ ni. Yaba, niluu Eko, nileeṣẹ to gba a siṣẹ naa wa, ṣugbọn ọjọ kẹta ti wọn gba a lo gbe ọkada naa sa lọ raurau, kọwọ awọn ọlọpaa to ba a l’Ogere, nipinlẹ Ogun.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kọkanla, oṣu keje yii, ni awọn ọlọpaa mu Emmanuel pẹlu ọkada naa. Wọn ko kọkọ fura si i, nitori bi wọn ṣe ni ko ko iwe ọkada naa wa lo ko o fun wọn lọwọ kan.

Nigba tawọn ọlọpaa yẹ iwe naa wo ni wọn ri i pe ọjọ kejila, oṣu keje, ni ọjọ ti wọn fi orukọ ọkada naa silẹ, eyi to tumọ si pe ọjọ keji ọjọ ti wọn mu un yii (Mọnde), ti ko ti i de rara ni wọn ti gba iwe ọkada naa lọdọ awọn eleto irinna.

Eyi mu ifura dani, ni wọn ba ni Emmanuel yoo ni lati tẹle awọn de teṣan awọn l’Ogere. O ni ẹru ileeṣẹ toun fẹẹ lọọ fun awọn to ni in wa lẹyin ọkada toun n gbe lọ gẹgẹ bii aṣẹ awọn ọga oun, ṣugbọn awọn ọlọpaa naa ni afi ko kọkọ de teṣan na, bawọn ba ridii ọrọ iforukọsilẹ ọkada rẹ to ruju yii tan, yoo maa lọ.

Nigba ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo titi, ọmọkunrin yii jẹwọ. O ni ayederu ni iwe toun ko kalẹ fun wọn naa. Emmanuel sọ pe funra oun loun kọ deeti to wu oun sori awọn iwe naa, toun si tun lo ayederu nọmba idanimọ si i.

O fi kun alaye ẹ pe oun fẹẹ gbe ọkada naa lọ koun maa lo o ni toun ni, idi toun fi da ọgbọn buruku ọhun ree. Bakan naa lo sọ fun wọn pe ọjọ kẹta ti wọn gba oun siṣẹ naa loun gbero lati gbe ọkada wọn lọ yẹn.

DPO teṣan ọlọpaa Ogere, CSP Abiọdun Ayinde, kan sawọn ileeṣẹ to gba Samuel siṣẹ, awọn eeyan naa si ṣalaye pe awọn ti n wa a latigba to ti gbe ẹru jade nileeṣẹ naa lati lọọ ja a sibi tawọn ran an lọ.

Maneja ileeṣẹ naa sọ pe awọn fi ẹrọ ti wọn fi maa n tọpasẹ ibi ti ọkada awọn ba wọlẹ si ( Tracker) si ara ọkada naa, o ni Emmanuel yii lo yọ ọ kuro lẹyin to jade lọgba awọn tan, to fi ṣoro lati tọpasẹ rẹ tabi mọ ibi to lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn da afurasi yii pada s’Ekoo, nibi to ti ji wọn lọkada, nibẹ ni wọn yoo ti ṣe ẹjọ rẹ, ti yoo de kootu ṣalaye ara ẹ.

Leave a Reply