Ojo lawọn eeyan n foun ṣe yẹyẹ, lo ba binu dana sun ara ẹ mọle

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kayeefi patapata lọrọ baba ẹni aadọta ọdun kan ti wọn porukọ rẹ ni Ojo Ogundeji si n jẹ fawọn eeyan latari bi ọkunrin naa ṣe wo sunsun, to si dana sun ara rẹ mọ’nu ile wọn to wa laduugbo Ọlọruntẹdo, Odòjọmu, niluu Ondo.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ojo ni wọn lo ti ara rẹ mọ inu yara kan ninu ile ọhun ko too sana si i lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, igbe oro to n jade lati ẹnu rẹ tawọn araale yooku n gbọ ni wọn fi sare mori le ọna yara rẹ, ṣùgbọ́n ti wọn ba ilẹkun ibẹ ni titi pa lati inu lọhun-un.

Kiakia lawọn eeyan naa ti ja ilẹkun wọle, ti wọn si sare gbe e digba digba lọ sile-iwosan ijọba to wa niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku fawọn to gbe e lọ.

Lanledi ile ọhun, Abilekọ Sabainah Ogundeji, ṣalaye fawọn oniroyin, o ni ilu Eko ni Ojo n gbe, nnkan bii ọsẹ meji sẹyin lo wa siluu Ondo fun ayẹyẹ Kérésìmesì ati ọdun tuntun.

O ni aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ni kinni naa kọkọ ti bẹrẹ si i pẹlu bo ṣe dana si abẹ àtẹ̀gùn ti awọn fi n gun oke ile alaja kan ọhun, to si duro gbagbaagba ti i pe ẹnikẹni ko gbọdọ pa ina naa.

Sabainah ni gbogbo awọn eeyan adugbo ti awọn n gbe ni wọn rọ jade lati waa ran awọn araale yooku lọwọ ki awọn too ri ina ọhun pa.

O ni Ojo ko ti i ku nigba tawọn araadugbo si ja ilẹkun wọle lati doola ẹ̀mí rẹ, alaye to ni o n ṣe fawọn eeyan ni pe oun pinnu ati pa ara oun latari yẹyẹ tawọn kan maa n fi oun ṣe lori isoro toun ni.

Wọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa Ẹnu-Ọwá leti, ti wọn si ti gbe oku ọkunrin naa pamọ si mọsuari ọsibitu ijọba ni asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Leave a Reply