Ọjọ mẹrin lawọn oṣiṣẹ yoo fi maa lọ sibi iṣẹ bayii nipinlẹ Kaduna

Faith Adebọla

 Ṣinkin ni inu awọn oṣiṣẹ ọba n dun lasiko yii nipinlẹ Kaduna, latari bi ijọba ṣe kede eto ilana iṣẹ tuntun fawọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ naa. ọjọ mẹrin pere ni wọn yoo maa fi ṣiṣẹ lawọn ọfiisi wọn ni gbogbo ọsẹ, bẹrẹ lati ọjọ ki-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii.

Gomina ipinlẹ naa, Mallam Nasir El-Rufai, lo paṣẹ ilana tuntun ọhun ninu atẹjade kan ti Oludamọran pataki rẹ feto iroyin and ijumọ-sọrọpọ, Ọgbẹni Muyiwa Adekẹyẹ, fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Wọn ni ipinlẹ Kaduna ti n ṣeto lati wọgi le iṣẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, fawọn oṣiṣẹ ọba jake-jado ipinlẹ naa, ati pe awọn maa bẹrẹ eto ọhun lẹkun-unrẹrẹ laipẹ.

Ṣugbọn ni bayii, bẹrẹ lati ọjọ ki-in-ni, oṣu Kejila, ọdun 2021 yii, ọjọ mẹrin pere ni kawọn oṣiṣẹ ọba fi maa waa ṣiṣẹ lọfiisi, ọjọ mẹrin naa yoo jẹ ọjọ Aje, Mọnde, si Ọjọbọ, Tọsidee, laarin aago mẹjọ aarọ si aago marun-un irọlẹ.

Wọn ni ile kaluku ni ko ti ṣiṣẹ ẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ki wọn si fi iṣẹ ti wọn ba ṣe sọwọ sibi to yẹ lori ẹrọ ayelujara.

Bijọba ṣe wi, eyi yoo fawọn oṣiṣẹ ọba laaye lati ni isinmi to pọ to, wọn aa tun ni akoko to pọ si i lati lo pẹlu idile kaluku wọn, ti wọn yoo raaye gbọ ti mọlẹbi wọn, wọn si le maa dọgbọn roko arojẹ tabi sin nnkan ọsin lẹhinkule ile kaluku wọn to ba ṣee ṣe.

Wọn ni ilana ṣiṣiṣẹ lati ile kaluku wa lara ọgbọn tawọn kọ lasiko ofin konilegbele to gbode nigba ti arun Korona kọkọ n ja bii iji lọdun to kọja.

Amọ ṣa o, ilana yii ko kan awọn ọmọleewe atawọn olukọ wọn, awọn yoo ṣi maa ṣiṣẹ fun ọjọ marun-un lọsẹ bi wọn ṣe n ṣe e bọ, titi ti ilana naa yoo fi kan wọn. Bẹẹ naa lawọn eleto ilera, eleto aabo ati awọn mi-in ti iṣẹ wọn jẹ akanṣe gbọdọ maa ba iṣẹ lọ bi wọn ti n ṣe e tẹlẹ, wakati mẹrinlelogun loojọ ni iṣẹ tiwọn.

El-Rufai ni awọn ti fun gbogbo awọn lọgaa-lọgaa lẹnu iṣẹ ọba ni ilana ati eto ti wọn maa ṣe lati le mu ki ofin tuntun yii kẹsẹ jari.

Leave a Reply