Ojo n jo lọ si ọgba ẹwọn gbere ti adajọ ju u si, eyi lohun to ṣe l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti, ti paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Ọgbẹni Ayegbusi Ojo, maa lọ si ẹwọn gbere lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan ni aṣepọ

Ile-ẹjọ naa, eyi ti Onidaajọ Johnson Adeyẹye, ṣe akoso rẹ sọ pe ẹsun kan ṣoṣo to rọ mọ ifipa-ba-ni-lo-pọ ni ọdaran naa n jẹ niwaju ile-ẹjọ yii.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun naa ṣe sọ, wọn ni ọdaran yii fọgbọn tan ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun ọhun wọ’nu yara rẹ lakooko to n dari pada lati ileewe, lo ba fipa ba a lajọṣepọ.

ALAROYE gbọ pe ọmọdebinrin naa ni ko le sọ fun awọn obi rẹ, ṣugbọn baba rẹ ṣakiyesi pe nnkan kan n ṣe e pẹlu bo ṣe ṣubu lulẹ, to daku, ti ẹjẹ si n jade lati oju ara rẹ.

Ni wọn ba sare gbe e lọ sileewosan, nibi ti ọmọbinrin naa ti pada jẹwọ pe Ojo lo fipa ba oun lo pọ lakooko ti oun n dari bọ lati ileewe. Aṣiri ti ọmọ yii tu lo mu ki wọn lọọ fi ọlọpaa mu ọkunrin naa, ti wọn si gbe e wa si ile-ẹjọ.

Ẹsun wọnyi ni ile-ẹjọ juwe gẹgẹ bii eyi to lodi sofin ifipa-ba-ni-lo-pọ to jẹ ofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2012.

Bakan naa ni oludari ẹka eto idajọ nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Julius Ajibare, pe ẹlẹrii mẹrin, to si tun ko ẹri mẹrin silẹ gẹgẹ bii ẹsibiiti lati fi gbe ẹjọ rẹ nidii.

Ọdaran naa sọrọ lati ẹnu agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Edmond Sunmonu, o si pe ẹlẹrii kan pere.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Adeyẹye, ṣalaye pe agbefọba naa ti ṣe ohun gbogbo lati fi idi ẹjọ ifipa-ba-ni-lo-pọ mulẹ ninu ẹjọ to ro nile-ẹjọ naa.

Lẹyin gbogbo atotonu, adajọ sọ Ojo si ẹwọn gbere, o ni ko lọọ lo iyooku ọjọ ọjọ aye rẹ lọgba ẹwọn.

Leave a Reply