Ọjọgbọn Adebayọ Bamirẹ di ọga agba tuntun fun Fasiti Ifẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn alakooso ileewe Ọbafẹmi Awolọwọ, Ileefẹ, ti kede Ọjọgbọn Simeon Adebayọ Bamirẹ gẹgẹ bii ọga agba tuntun fun ileewe naa bayii.

Iyansipo rẹ gẹgẹ bi alaga igbimọ oluṣakoso ileewe naa, Owelle Oscar Idoko, ṣe wi, yoo bẹrẹ lọjọ keje, oṣu Kẹfa ọdun yii.

Asiko ti ọga to wa nibẹ lọwọlọwọ, Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogunbọdẹde, yoo wa sopin lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii lẹyin to ti lo ọdun marun-un lori ipo naa.

Owelle ṣalaye pe ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun to kọja, ni awọn fẹnu ko ninu igbimọ lati bẹrẹ igbesẹ nipa ẹni ti yoo jẹ ọga agba tuntun, wọn si fi ikede sita nibaamu pẹlu ilana ti wọn fi n wa eeyan si ipo yii.

O ni ninu ipade kan tawọn ṣe lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii, lawọn ti ṣayẹwo iwe-ẹri awọn eeyan ogun ti wọn fi ifẹ han si ipo naa, lẹyin naa lawọn si mu awọn mẹrindinlogun.

Lẹyin eyi ni awọn ọmọ igbimọ bẹrẹ ifọrọwerọ pẹlu awọn eeyan naa laarin ọjọ kẹrinla si ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹta ọdun yii, awọn mẹẹdogun ni wọn farahan, nigba ti ẹnikan to ku ṣe tiẹ lati ori ikanni ayelujara.

Lẹyin ayẹwo finni-finni si iwe-ẹri awọn eeyan naa ati ifọrọwerọ pẹlu wọn, wọn mu eeyan mẹta ninu wọn fun awọn igbimọ lati yan ẹni to kunju oṣuwọn ju lọ fun ipo naa.

Laarin awọn mẹta yii ni wọn ti mu Bamirẹ. Ọmọ bibi ilu Ọyan, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọṣun, ni, ẹka imọ nipa eto ọgbin ni OAU lo si ti n ṣiṣẹ ki wọn too yan an l’Ọjọbọ, Tọsidee.

Leave a Reply