Ọjọgbọn Adejọrọ di Alafin ti Afin Akoko tuntun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn eeyan ilu Afin Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, ko le pa idunnu wọn mọra lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ yiyan Ọjọgbọn Abdulroheem Mustapha Adejọrọ Ilufẹmiloye gẹgẹ bii Alafin tuntun tilu ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ti bẹrẹ eto ọhun diẹdiẹ kí wọn too parí rẹ síbi tí Kabiyesi tí wọ Ipebi lọ, nibi ti wọn yoo ti ṣe awọn etutu yooku fun un ki wọn too gbe ade le e lori.

Idile mẹta lo n jọba ni Afin Akoko, Udiolojudo, Asigi ati Ode-Gbangba gẹgẹ bii alaye ti Alaaji Ibrahim Kilani to jẹ ọkan ninu awọn agba ilu ṣe.

O ni idile Udiolojudo ni Ọba Idris Ọlọruntẹgbẹ Suberu to waja ni nnkan bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin ti wa, nigba ti ọba tí wọn sẹsẹ yan yii jẹ ọmọ idile ọba Asigi.

Agba akọroyin ọhun ni aifimọṣọkan idile Asigi lori ẹni to yẹ ki wọn fa kalẹ gẹgẹ bii ọmọ oye lo mu kọrọ ati yan ọba mi-in pẹ to bẹẹ, leyii to fun Ọmọọba Idris Funmilayọ lanfaani lati wa lori itẹ gẹgẹ bii Adele-Ọba lati igba ti baba rẹ ti gbesẹ.

Awọn afọbajẹ mẹrin lo ni wọn pada dibo fun ọba ti wọn sẹsẹ yan ọhun, nigba tawọn meji pere fọwọ si ẹnikan to pe ara ẹ ni Ọmọọba Ganiyu Adegboyega to jẹ igbakeji ọga agba nileeṣẹ eto iroyin ati itanilolobo l’Abuja.

Alaaji Kilani ni ẹbẹ oun sawọn ọmọ oye ati gbogbo ara ilu ni pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu Ọba Adejọrọ fun anfaani gbogbo eeyan.

Ọba tuntun naa ni wọn lo jẹ ọkan ninu awọn olukọ agba to ṣiṣẹ pẹlu National Open University saaju iyansipo rẹ.

 

Leave a Reply