Ọjọgbọn Clement Adebọoye di ọga agba tuntun fun Fasiti Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alaga igbimọ alakooso Fasiti Ọṣun, Mallam Yusuf Ali, ti kede Ọjọgbọn Ọdunayọ Clement Adebọoye gẹgẹ bii ọga agba tuntun kẹrin fun fasiti naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ile-ẹkọ ọhun, Ademọla Adesọji, fi sita laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo ti ṣalaye pe lẹyin ti Alaamojuto agba fasiti naa, Gomina Adegboyega Oyetọla, fọwọ si yiyan Adebọoye ni wọn kede orukọ rẹ.

Atẹjade naa ṣalaye pe ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun 1966, ni wọn bi Ọjọgbọn Adebọoye, eyi to tumọ si pe ọmọ ọdun mẹrindinlọgọta ni.

Ọjọgbọn ninu eto ọgbin (Plant Physiology), ni ọga tuntun naa, o si ti wa ninu eto-ẹkọ lati nnkan bii ọdun mẹrindinlọgbọn sẹyin. O tun jẹ ọkan lara awọn igbakeji ọga Fasiti Ọṣun ki wọn too yan an sipo tuntun yii.

O ti fi ọpọ ọdun jẹ ọjọgbọn to n ṣiṣẹ lawọn fasiti kaakiri orileede Naijiria, Germany, Canada, to si ti ṣiṣẹ papọ pẹlu United Nations ri.

Mallam Yusuf Ali sọ pe oniruuru ipenija ni igbimọ naa koju lasiko ti wọn n gbe igbesẹ lati yan ọga agba tuntun naa, sibẹ, pẹlu ipinnu ọkan, wọn yan ẹni to kunju oṣunwọn sipo naa.

O ni oun nigbagbọ kikun ninu awọn amuyẹ ti Ọjọgbọn Adebọoye ni, oun si mọ pe yoo lo iriri rẹ lati mu idagbasoke ba fasiti naa.

Ali waa parọwa sawọn igbimọ alakooso ati awọn oṣiṣẹ fasiti naa lati fọwọsowọpọ pẹlu ọga agba tuntun naa.

Leave a Reply