Ọjọgbọn Fọlaṣade Ogunṣọla di obinrin akọkọ ti yoo di Adele ọga agba Fasiti Eko

Faith Adebọla, Eko

Ọjọgbọn Fọlaṣade Tolulọpẹ Ogunṣọla ti jawe olubori ninu ibo ti igbimọ alakooso Fasiti Eko, UNILAG, di lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lati yan ẹni ti yoo jẹ adele ọga agba (Acting Vice-Chacellor) ileewe naa, wọn si ti bura fun un lẹyẹ-o-sọka.

Igba akọkọ ree ti obinrin yoo di ipo ọga agba UNILAG mu.

Nibi ipade pataki kan to waye lọjọ ọhun nibaamu pẹlu aṣẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari pa ninu lẹta kan to kọ si igbimọ naa lori fa-a-ka-ja-a ti iyansipo adele ọga agba Ọjọgbọn Ṣoyọmbọ mu dani lo fa igbesẹ tuntun ti wọn fi yan akọni obinrin yii.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, awọn igbimọ alaakoso yunifasiti naa ti wọn n pe ni Senate ni wọn pepade, ti awọn Purofẹsọ mẹtadinlaaadọsan-an si pesẹ sibi ipade naa. Lẹyin ijiroro, wọn dabaa ẹni meji lara wọn fun aaye to ṣi ṣilẹ ọhun, Abilekọ Fọlasade Ogunṣọla ati Ọjọgbọn Ben Ogbolafor.

Eyi lo mu ki wọn dibo, ti Abilekọ Ọgunṣọla si ni ibo marundinlaaadoje, nigba ti ẹni keji rẹ ni ibo mọkanlelọgbọn pere. Alaga igbimọ alakooso naa, Ọjọgbọn Chioma Agomo, lo kede esi ibo, o si fidi ẹ mulẹ pe Abilekọ Ogunṣọla lo yege.

Ṣaaju iyansipo rẹ yii, Ogunsọla ni igbakeji ọga agba (Deputy Vice-Chancellor) ni ẹka iṣẹ idagbasoke fasiti ọhun, lati ọdun 2017 lo si ti wa nipo naa.

Ọdun 1958 ni wọn bi adele ọga agba tuntun yii, ọjọgbọn ninu ẹkọ nipa ilana iṣegun awọn kokoro aifoju ri (Professor of Medical Microbiology), oun ni obinrin akọkọ ti yoo wa nipo ọga agba kọlẹẹji ẹkọ nipa iṣegun fasiti ọhun  (University College of Medicine), Idi-Araba, l’Ekoo. Ọpọ iwadii imọ ijinlẹ lori didena awọn arun aṣekupani bii HIV, AIDS ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ti ṣe.

Ṣaaju ni gbọnmi-si-i omi-o-to ti waye lori iyọkuro ati iyansipo ọga agba fasiti ọhun, lẹyii to mu ki Aarẹ Buhari paṣẹ pe ki Alaga igbimọ apaṣẹ fasiti naa, Ọjọgbọn Wale Babalakin, ṣi yẹba diẹ na. Bakan naa ni wọn ni ki ọga agba ti wọn yọ nipo naa, Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipẹ, ati ẹni tawọn igbimọ apaṣẹ naa lawọn yan rọpo, Ọjọgbọn Theophilus Ṣoyọmbọ, ṣi wa ibi kan jokoo si titi ti igbimọ oluwadii ti Aarẹ gbe kalẹ lati tu iṣu desalẹ ikoko ohun to n fa aigbọra-ẹni-ye to waye naa yoo fi jabọ iṣẹ wọn.

Ireti wa pe iyansipo yii yoo mu ki omi alaafia fasiti to ti n daru tẹlẹ bẹrẹ si i toro bayii.

CAPTION

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: