Ọjọgbọn Ọṣinbajo yoo ṣefilọlẹ Gbọngan Aṣa ati Iṣe Yoruba lagbaaye ninu ọgba Fasiti Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gbogbo eto lo ti to bayii, nipa bi Igbakeji Aarẹ lorilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, yoo ṣe ṣẹfilọlẹ Gbọngan Aṣa ati Iṣe Yoruba lagbaaye, ti wọn pe ni ‘Ile (International Centre for Yoruba Arts and CultureYoruba), ni Yunifasiti ilu Ibadan, iyẹn lọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii. (23- 11-21)

Gẹgẹ bi atẹjade to ti ọwọ awọn alaṣẹ eto naa wa ṣe wi, Ọọni Ile-Ifẹ; Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, yoo kun Igbakeji Aarẹ lọwọ nibi ayẹyẹ yii, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta si ni Alaga.

Onibẹta leto yii,  International Centre for Yoruba Arts And Culture (INCEYAC), pẹlu ẹka ti wọn ti n kẹkọọ ede ilẹ Adulawọ ( The Institute of African Studies) ati ẹka ede Yoruba ni Yunifasiti naa ( Yoruba Language Centre) lo gbe e kalẹ pẹlu alaye pe wọn yoo ṣiṣọ loju eegun ibi ti wọn yoo maa lo na fun eto yii.

Wọn yoo ṣatupalẹ ohun ti ile Agbaye Yoruba yii wa fun gan-an, Ọjọgbọn Ọṣinbajo yoo si fi ipilẹ ile naa lelẹ loju gbogbo aye.

  Bi wọn ba waa pari ile alara yii o, yoo ni ile ikawe nla teeyan tun ti le ya iwe ka,(Library). Yoo ni ibudo ti wọn yoo maa tọju awọn iwe atayebaye si,(Archive), yoo ni ile iṣẹmbaye ti awọn nnkan atijọ yoo maa wa ( Museum), aaye igbafẹ yoo wa nibẹ pẹlu,(Recreation Centre), ibudo ẹka ayelujara teeyan ti le to nnkan pọ niṣẹju aaya yoo wa nibẹ, abule awọn onitiata ti wọn ti le yaṣẹ eyikeyii to ba wu wọn ( film village) ati igbo atọwọda to duro digbi bii igbo aiwọ yoo si tun wa nibẹ pẹlu.

Ọkan lara awọn olufọkatan INCEYAC to tun jẹ Oludasilẹ iwe iroyin ALAROYE, Alao Adedayọ, ṣalaye pe ọkan pataki ninu awọn ibudo teeyan ti le ṣewadii iṣẹ ọpọlọ ni ibi ti Ọṣinbajo fẹẹ ṣi yii.

O ni awọn oluwadii bii olukọ fasiti, awọn akẹkọọ, onkọwe, akọroyin, onpitan atawọn eeyan laarin ilu yoo jẹ anfaani ẹ gidi lati ṣiṣẹ idagbasoke orilẹ-ede yii.

“Bo ṣe jẹ pe awa la n fi ede Yoruba kọroyin ju lagbaaye lonii, ati nitori ajọṣẹpọ wa pẹlu ede yii, pẹlu iṣẹ-ọna, aṣa ati iṣe awọn Yoruba nipasẹ iwe iroyin wa-Alaroye, a le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe ko sibi kan lagbaaye lonii tawọn oluwadii abi ẹnikẹni ti le jokoo ṣewadii lori aṣa Yoruba atawọn eeyan rẹ.

“Awa si gbagbọ pe o yẹ ka ni iru ẹ kan to le ran wa lọwọ ninu kikọ ilu wa, fun idi eyi, ohun iwuri gidi ni pe INCEYAC ati Yunifasiti Ibadan patẹ eyi papọ.

Bẹẹ la nireti pe awọn ọmọ Yoruba lọkunrin atobinrin, atawọn eeyan mi-in ti wọn jẹ ọrẹ ọmọwe yii yoo dide iranlọwọ si agbekalẹ yii, wọn yoo da si i lọna ti wọn ba le gba fi ran wa lọwọ”

Bẹẹ ni Adedayọ wi.

Leave a Reply