Ojoojumọ lọkọ mi fẹẹ maa gun mi bii ẹṣin, agbara temi o si gbe e, mi o fẹ ẹ mọ-Jẹlilat

Faith Adebọla, Eko
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa niluu Igando, nipinlẹ Eko, ti pin gaari fun tọkọ-taya kan, Ọgbẹni Taofeek Muritala, ati iyawo rẹ, Abilekọ Jẹlilat Muritala, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin yii, wọn ni ajọṣe wọn o le bọ si i mọ lẹyin ọdun mẹwaa ati ọmọ mẹta.
Ọgbẹni Muritala lo gba kootu lọ lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun to kọja, o ni ki wọn ba oun tu igbeyawo wọn ka.
Baale ile naa fẹsun kan iyawo rẹ pe onijangbọn ẹda kan ni, o lagidi bii apaara, ki i mojuto awọn ọmọ rara.
O ṣalaye pe: “Ọdun 2022 ni wahala ti bẹrẹ, nigba to ṣẹṣẹ bi akọbi wa, ọkada ni mo n gun, ọgọrun-un Naira (N100) ni mo n fun un lojumọ nigba yẹn, tori mo gbọdọ sanwo dilifa fẹni to ni ọkada naa lojoojumọ.
“Laarin kan, mi o ri owo fun un, lo ba bẹrẹ si i ba mi ja, o ni gbese ti mo jẹ oun ti di ọgọrun-un mẹsan-an Naira (N900), bo ṣe lọṣọ mọ mi lọrun niyẹn, o ni mi o ni i jade nile lai san gbese naa. Ọpẹlọpẹ awọn aladuugbo to waa gba mi silẹ, o faṣọ ya mọ mi lọrun danwo.
“Ko tun fẹẹ ri imi iya mi laatan, o koriira mama mi, o ni mama mi maa n rojọ ju nipa ounjẹ ti wọn ba waa ki wa, gbogbo igba tiyaa mi ba ṣabẹwo si wa, ija ni, ni mo ṣe sọ fun wọn pe ki wọn ma wa sọdọ wa mọ.
“Bo ṣe wu u lo n ṣe, bo ba jade lọ, ko ni i dagbere, igba to ba si wu u lo maa de. Ko naani awọn ọmọ to bi, emi ni mo maa n tọju wọn, ti mo n ko wọn lọ sileewe. Bii ẹhanna lo maa n ṣe tija ba ti waye laarin wa, o ti pago mọlẹ tori mi ri, aimọye igba lo maa n yọbẹ si mi, pe niṣe lo loun maa gun mi pa. Eeyan o si le ba a sọrọ laye yii ko gbọ, ki i ṣatunṣe,” bẹẹ lẹjọ ti baale yii ro mọ iyawo rẹ ṣe lọ.
Iyawo naa, Jẹlilat, fesi sọrọ tọkọ rẹ sọ, o ni:
“Ẹ ma da a lohun o, ọtọ ni nnkan to ṣẹlẹ, ko sohun to n dija silẹ laarin wa ju ọrọ ibalopọ lọ, ojoojumọ lo fẹẹ maa gun mi bii ẹṣin, agbara temi o dẹ gbe ibasun ojoojumọ.
“Mi o si ba mama ẹ ja, ṣugbọn ko sohun ti mo ṣe ti mọ ọn ṣe lọdọ mama yẹn, awọn nikan naa ni wọn maa n ṣaroye nipa mi ṣaa, awọn nikan ni mi o mọ ilẹ wọn ọn gba laarin mọlẹbi ọkọ mi.
“Ṣugbọn ni tododo, ko sifẹẹ mọ laarin wa. Ọkọ mi ti fẹyawo mi-in pamọ ti mo mọ, toun naa o si le jiyan ẹ, ifẹ ẹ ti yọ lọkan mi, mo ti n ba igbesi aye mi lọ.”
Aarẹ ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Kọledoye Adeniyi, lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni ẹri fihan pe irinajo ifẹ laarin tọkọ-taya naa ko ṣe e dọgbọn si mọ, wọn si tun ti mu tawọn ọmọ wọn mọ ọn.
Adajọ lo lodi fun iyawo naa lati fi ibalopọ du ọkọ rẹ, iba jẹ ojooojumọ lo fẹẹ maa sun mọ ọn, o leyii wa lara ohun to jẹ kigbeyawo naa fori ṣanpọn. O leyii lo mu ki ọkọ naa fẹyawo mi-in sita, lati le tẹ ara ẹ lọrun.
“Pẹlu bọrọ ṣe ri yii, o han pe igbeyawo yii ko latunṣe mọ, tori naa, ile-ẹjọ yii tu yin ka.
“Mo paṣẹ ki olupẹjọ san ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000) gẹgẹ bii owo ikọsilẹ fun iyawo rẹ, ko si tun san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) fun un lati gba ile ti yoo maa gbe.”
Adajọ tun paṣẹ pe ki ọkọ naa bojuto awọn ọmọ, o si gbọdọ ran wọn niwee bo ṣe yẹ.
O lẹnikẹni to ba tẹ aṣẹ ile-ẹjọ naa loju n fi ẹwọn oṣu mẹfa run’mu ni.

Leave a Reply