Faith Adebọla
“O da bii ẹni pe ijọba apapọ ti juwọ silẹ fawọn to n fojoojumọ pariwo pe ki wọn kede awọn janduku agbebọn gẹgẹ bii afẹmiṣofo, paapaa awọn oniroyin lati apa ibi kan lorileede yii. Ṣugbọn orukọ yoowu ki wọn pe wọn, ko le mu iyatọ kankan wa, ko si le tu irun kan lara wọn, tori ko too di asiko yii nijọba ti n doju ija kọ wọn bii ẹni pe afẹmiṣofo ni wọn.”
Eyi lawọn ọrọ kabiti kabiti to n jade lẹnu ilu-mọ-ọn-ka aṣaaju ati olukọ ẹsin Musulumi lapa Oke-Ọya ilẹ wa, Sheikh Ahmed Abubakar Gumi, nigba to n sọ ero rẹ lori bi ile-ẹjọ giga apapọ kan l’Abuja ṣe kede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, pe afẹmiṣofo ati eeṣin-o-kọ’ku lawọn janduku, ọwọ iru ẹni ti wọn jẹ si ni kijọba fi mu wọn.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ Gumi lori eto iroyin, Malam Tukur Mamu, fi lede lorukọ ọga ẹ, Gumi ni “ko siṣoro kan ninu orukọ yoowu kijọba pe wọn, yiyi orukọ wọn pada ko le tu irun kan lara wọn tori ọrọ to wa nilẹ yii ju ọrọ orukọ lọ.
Tẹ ẹ ba ranti, ijọba ti figba kan pe ẹgbẹ IPOB to n ja fun idasilẹ Biafra nilẹ Ibo ni ẹgbẹ afẹmiṣofo, wọn ni tẹrọriisi (terrorists) ni wọn, wọn tiẹ tun gba aṣẹ kootu kan lati kede wọn bẹẹ, wọn si doju ogun kọ wọn, ṣugbọn ki lo tẹyin ẹ yọ.
Awọn ajọ agbaye fara mọ ikede ijọba apapọ, wọn o si tori ẹ ṣatilẹyin fun ijọba tabi ki wọn gbogun ti awọn IPOB. Abi awọn IPOB ko si ninu awọn to lọọ ṣewọde nibi apero agbaye Iparapọ Awọn Orileede l’Amẹrika laipẹ yii.
Tori ẹ, orukọ yoowu ki wọn pe wọn, ko ja mọ nnkan kan, ko tiẹ nitumọ rara. Ṣe tẹrọriisi ti wọn pe awọn IPOB ti sọ wọn di ọmọ orileede mi-in ni, ọmọ Naijiria ṣi ni wọn, wọn le lọ lati ibi kan si ikeji.
Mo lero pe ikede tile-ẹjọ ṣe yii ko ni i mu ki wọn bẹrẹ si i pe awọn darandaran naa ni tẹrọriisi ṣa. Pẹlu bi awọn ologun ṣe n doju ija kọ wọn ṣaaju asiko yii, iyatọ wo lo ti mu wa, ṣe iyẹn ti dawọ ijinigbe, ipaniyan akọlu tawọn janduku n ṣe duro ni. Pipe tile-ẹjọ pe wọn ni tẹrọriisi yii ko le mu ki wọn jawọ ninu iwa wọn rara.
Iṣoro awọn janduku agbebọn ki i ṣe ohun ta a le fi ija ati ogun yanju rara. Awa ti ba wọn sọrọ, a ti ri ibi ti nnkan ti wọ wa, a si ti gba ijọba apapọ lamọran pe ki wọn ba awọn janduku sọrọ lori nnkan to n bi wọn ninu, ki wọn si ṣe ẹtọ fun wọn, ki wọn tun igbe aye wọn ṣe. Iyẹn ni alaafia fi wa lagbegbe Niger-Delta lonii, nigba ti ijọba ba wọn fikun lukun, ti wọn si ṣẹtọ fun wọn.
Ojoro wa ninu bi wọn ṣe n pin ọrọ ati alumọọni orileede yii, afi ti a ba ṣe ṣatunṣe si i, ti nnkan lọ ni dọgba dọgba. Gbogbo wa ni iwa buruku awọn janduku yii kan, ṣugbọn kọrọ too de ibi to de yii, oju ti pọn awọn Fulani ju ni Naijiria yii, afi ka tọju wọn atawọn maaluu wọn.”
Bẹẹ ni Gumi ṣe sọ ero rẹ.