Ojubọrọ ko ṣee gbọmọ lọwọ ekurọ, awa la fi wọn sipo, awa la maa rọpo wọn-Tinubu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

funpo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Aśiwaju Bọla Hammed Tinubu, ti sọ pe ko si idiwọ kankan ti ẹnikẹni le ṣeto rẹ to le di erongba oun lati di aarẹ orileede yii lọwọ.

Nibi eto ipolongo ibo rẹ to waye ni Nelson Mandela Freedom Park, niluu Oṣogbo, lo ti sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun yii. Tinubu ni koda bi wọn sọ owo Naira di kọbọ, oun yoo wọle ibo naa.

Tinubu, ẹni ti awọn minisita, awọn gomina atawọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii ba kọwọọrin sọ pe awọn araalu ti ṣetan lati fẹsẹ rin lọ sibudo idibo lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni, “Ojubọrọ kọ la fi n gba ọmọ lọwọ ekurọ. A ki i ṣe ọmọ ale. Awa la fi wọn sibẹ, awa naa la maa rọpo wọn, a maa dibo, a maa wọle.

“Ko si nnkan ti wọn le ṣe, koda, bi wọn sọ owo Naira di kọbọ, ibi ti a ti maa dibo ko jinna silee wa, a maa fẹsẹ rin lọ sibẹ, ibikibi to wu ki wọn gbe apoti idibo si, a maa debẹ.

“Bi ẹ ba sọ pe ẹ maa mu nnkan su wa, a ti rin jinna, a maa duro pẹlu ipinnu ọkan labẹ bo ti wu ko ri. Gbogbo ẹyin ọdọ ti ẹ n wa iṣẹ lẹ maa riṣẹ, a maa da oriṣiiriṣii ileeṣẹ silẹ fawọn ọmọ wa.

“Ẹyin ti ẹ wa nileewe, ẹ pe mi lọmọ ale ti ẹ ba lo ju ọdun mẹrin lọ lẹnu ẹkọ yin, a maa sanwo ileewe yin, a si maa ya yin lowo lati fi ṣiṣẹ”.

Tinubu tun fi awọn ọmọ ẹgbẹ naa lọkan balẹ nipinlẹ Ọṣun, o ni didun lọsan yoo so fun wọn nitori ẹrin aringbẹyin lo maa n ni ayọ ninu.

Leave a Reply