Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n koroyin yii lọrọ gendekunrin kan bayii, Ọgbẹni Suleiman Abubakar, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), ti wọn ju sọgba ẹwọn ṣi n ya awọn eeyan lẹnu.
Bẹẹ ko sohun meji to jẹ kọrọ Suleiman maa jọọyan loju ju pe ohun ti ko to nnkan lo sọ ọ dero ẹwọn. Redio ni ọn lo lọọ ji lagbegbe Dawaki, niluu Abuja, ọhun naa lo si sọ ọ dero ọgba ẹwọn bayii.
Adajọ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ Saminu Suleiman, ni bi ọdaran yii ko ba fẹẹ lọọ fẹwọn jura, ko san ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) Naira, kiakia, bi bẹẹ kọ, kawọn ọlọpaa lọọ ju u sọgba ẹwọn ilu Abuja ni.
Lọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun yii, ni Ọgbẹni Suleiman Abubakar lọ sile Ọgbẹni Abdulrahman Myheimimu, to wa lagbegbe Dawaki, niluu Abuja, to si ji redio alagbeerin kan bayii ti wọn n pe ni MP3, eyi ti wọn sọ pe owo rẹ jẹ ẹgbẹrun marun-un Naira (N5,000), ko too di pe ọwọ pada tẹ ẹ.
Ohun ti agbofinro to ṣoju ijọba ni kootu, Ọgbẹni Ọlaonipẹkun Babajide, sọ lo tubọ ko ba Ọgbẹni Suleiman Abubakar si i. Ọlọpaa naa ṣalaye pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti yoo jale, ti ọwọ si n tẹ ẹ, ati pe o tun lẹjọ ni kootu naa tẹlẹ.
Ọrọ ti ọlọpaa naa sọ lo mu ki Suleiman rawọ ẹbẹ si adajọ pe ko ṣiju aanu wo oun, o ni ko ro ti akoko oṣu aawẹ Ramadan to wa nita yii mọ oun lara.
Ọlọpaa naa sọ pe ẹṣẹ ti Suleiman ṣẹ ki i ṣe ohun to daa rara, ati pe ijiya nla gbaa lo wa fun ẹni yoowu to ba ṣe iru ẹ lawujọ.
Ọrọ ti ọlọpaa yii sọ lo mu ki adajọ naa paṣẹ pe ki Suleiman lọọ ṣẹwọn oṣu mọkanlelogun, pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn, tabi ko sanwo itanran ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira.