Ọkada lawọn eleyii lọọ ji gbe tọwọ fi tẹ wọn ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi mẹta; Abdullahi Yaro, Abdulganiu Muhammed ati Baki Adamu, ni wọn ti ko si pampẹ ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, nipinlẹ Kwara bayii. Ẹsun jiji ọkada Bajaj gbe lagbegbe Kpaulu, laduugbo Gure, niluu Kosubosu, nipinlẹ Kwara ni wọn fi kan wọn.

Alukoro ileeṣẹ NSCDC, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021, lẹni to ni ọkada naa, Ọgbẹni Yahaya Abdulateef, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, fi to ileeṣẹ NSCDC to wa ni Kosubosu leti pe awọn ole wa sile oun, ti wọn si ji ọkada oun gbe sa lọ.

Afọlabi ni lọgan lawọn gbera pẹlu iranlọwọ awọn fijilante ilu naa, awọn si ri Abdullahi Yaro, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, toun naa n gbe ni Kpaulu, laduugbo Gure, nibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ mu.

O nigba tawọn fọrọ wa a lẹnu wo, o darukọ Abdulganiu Muhammed, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, pe o wa lara awọn, kia lawọn lọọ gbe iyẹn naa.

Bakan naa, Yaro tun sọ fawọn oṣiṣẹ NSCDC pe ile ẹni kẹta, Baki Adamu, to n gbe ni Buregi Kpane, lagbegbe Gure, lawọn gbe ọkada tawọn ji gbe naa pamọ si.

O ni bawọn oṣiṣẹ NSCDC ṣe de ile iyẹn loootọ, wọn ba ọkada naa nibẹ. Bi wọn ṣe gbe Adamu ati ọkada ti wọn ji gbe ọhun lọ si tesan niyẹn.

Ọkunrin yii ni ẹni to ni ọkada naa ti yẹ gbogbo rẹ wo, o si ko awọn iwe rẹ wa lati fidii rẹ mulẹ pe loootọ, oun loun ni i.

O ni ẹka to n mojuto eto ofin ati idajọ nileeṣẹ NSCDC ti n gbe igbesẹ lati ko awọn afurasi naa lọ si kootu.

Leave a Reply