Ọkada mẹrindinlaaadọrun-un tun ha sọdọ awọn agbofinro l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ọkada bii mẹrindinlaaadọrun-un nijọba gba nidii awọn to n gun wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, kaakiri awọn agbegbe ipinlẹ Eko, wọn lawọn ọlọkada naa ya eleti ikun, awọn ọna tijọba ti ka leewọ fun wọn ni wọn n gba.

Awọn ikọ amuṣẹya tijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ ta ko awọn to n rufin irinna nipinlẹ ọhun (Lagos State Environmental and Special Offences Unit Taskforce), eyi ti CSP Ṣọla Jẹjẹloye ṣe alaga rẹ ni wọn mu awọn ọkada naa.

Awọn agbegbe bii Ikẹja, Ọba Akran, Yaba, Oyingbo, Surulere, Allen Avenue ati awọn opopona mi-in ni wọn lawọn ti mu wọn.

Jẹjẹloye ni niṣe lọpọ awọn to n gun ọkada naa maa n fi ọkada wọn silẹ, ti wọn aa si fẹsẹ fẹ ẹ, kawọn agbofinro ma baa fi pampẹ ofin gbe wọn. Mọto gagara kan ni wọn fi n loodu awọn ọkada naa lọ sahaamọ wọn n’Ikẹja.

Wọn ni niṣe lawọn maa lu awọn ọkada naa ni gbajo laipẹ tile-ẹjọ ba ti fọwọ si i, gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin irinna ipinlẹ naa.

Leave a Reply