Ọkada ni Taofeek ji gbe tọwọ NSCDC fi tẹ ẹ lọjọ ọdun Ileya n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu adigunjale kan, Saliu Taofeek, ninu ọja igbalode kan to wa ni agbegbe Taiwo, niluu Ilọrin, lọjọ ọdun Ileya, lẹyin ọjọ pipẹ to ti ji ọkada gbe, to si sa lọ, ti ajọ ọhun si ti kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti wọn wa lati igba naa lọhun.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, fi lede ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lo ti sọ pe arakunrin ọhun ji ọkada gbe ninu oṣu karun-un, ọdun yii, to si sa lọ pẹlu ọkada naa. Gbogbo igbiyanju ajọ NSCDC, mu un lo ja si pabo, eyi lo mu ki ajọ naa kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa. Ṣugbọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ti i ṣe ọjọ ayẹyẹ ọdun Ileya, ni ọwọ tẹ ẹ ni ọja igbalode kan to wa ni agbegbe Taiwo, niluu Ilọrin, lasiko to lọ raja ni ibẹ.

 

Afọlabi fi kun un pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, awọn yoo foju afurasi naa ba Ile-ẹjọ.

 

Leave a Reply