Ọkan lara awọn ọlọdẹ tawọn agbebọn yinbọn fun ni Ifẹwara ti ku o

 

Florence Babaṣọla

 

Ọkan lara awọn ọlọdẹ ti wọn n ṣọ awọn oyinbo meji tawọn agbebọn ji gbe nibudo iwakusa kan labule Itikan niluu Ifẹwara ti jade laye bayii.

Bakan naa ni awọn agbebọn naa ti beere miliọnu mẹwaa naira lati tu awọn oyinbo mejeeji; Messrs Zhao Jian ati Wen, silẹ lahamọ ti wọn wa.

Lọjọ Aje, Móńdé, ọsẹ yii, lawọn agbebọn ya bo ibudo iwakusa naa, wọn yinbọn fun awọn ọlọdẹ meji ti wọn n ṣọ awọn oyinbo naa, lẹyin ti wọn ji awọn oyinbo ọhun gbe lawọn ara abule naa gbe awọn ọlọdẹ naa lọ si ọsibitu, ṣugbọn iwadii fi han pe ọkan lara awọn ọlọdẹ naa ti ku.

Ọkan lara awọn adari ẹgbẹ awọn ọlọdẹ, Hunters Group of Nigeria, ẹka tipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun, sọ pe ileewosan ni ọkunrin naa ku si.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla sọ pe awọn ọlọpaa atawọn ikọ alaabo yooku ti wa ninu igbo latọjọ tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lati ri awọn oyinbo naa gba kalẹ.

Ọpalọla ṣalaye pe loootọ ni wọn ti beere miliọnu mẹwaa naira (#10m) lati tu awọn oyinbo naa silẹ, ṣugbọn ireti wa pe ọrọ naa yoo loju laipẹ.

 

Leave a Reply