Ọkan ninu awọn alatilẹyin Obaseki ja bọ lẹyin ọkọ nibi to ti n dawọọ idunnu l’Edo

Ko ti i sẹni to ti i le sọ boya ọmọkunrin naa wa laaye tabi o ti ku. Iyẹn ọmọkunrin kan to jẹ ọkan ninu awọn alatilẹyin Gomina ipinlẹ Edo to tun n dije ninu ibo to n lọ lọwọ, Godwin Obaseki, to ja bọ lẹyin ọkọ lasiko to n fi idunnu rẹ han si esi idibo agbegbe rẹ ti wọn ni gomina naa rọwọ mu nibe.

Ni nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ni iṣẹlẹ naa waye ni ileewe alaakọbẹrẹ kan ti wọn n pe ni Ugbekun Primary School.

Nibi ti ọdọmọkunrin naa ti n yọ ayọ yii lo ti ja bọ lẹyin ọkọ agbarigo. Bo tilẹ jẹ pe mọto naa ko duro, awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to wa nitosi sare gbe e lọ sileewosan to wa nitosi, ṣugbọn ko sẹni to ti i le sọ boya o ku ni tabi o wa laaye.

Leave a Reply