Ọkan ninu awọn Olori Ọba Aromọlaran jade laye

Florence Babaṣọla

Ọkan lara awọn iyawo Ọwa Obokun ti ilẹ Ijeṣa, Ọba Gabriel Adekunle Aromọlaran, Olori Ọlanikẹ, ti dagbere faye bayii.

Ileewosan Federal Medical Center, Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, la gbọ pe olori naa dakẹ si lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii lẹyin aisan ranpẹ.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, la gbọ pe wọn tu’fọ iku Olori ọhun, ẹni to jẹ olukọ-fẹyinti nileewe girama kan niluu Ileṣa, fun kabiesi.

Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, Ọnarebu Wale Adedoyin to jẹ aṣofin to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Iwọ-Oorun Ileṣa, ṣapejuwe Olori Ọlanikẹ gẹgẹ bii ẹni to ko gbogbo eeyan mọra.

Adedoyin ba Ọba Aromọlaran kẹdun iku naa, o si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: