Ọkan pataki lara iran to le ba wa gbogun ti wahala eto aabo lorileede yii ni awọn Fulani-Oluwoo 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọba Adewale Akanbi, Oluwoo tilu Iwo, ti ke si awọn Fulani darandaran atawọn Bororo ti wọn n gbe niluu Iwo ati ayika rẹ lati dẹkun kiko maaluu wọn jẹko kaakiri oko oloko.

Oluwoo sọrọ yii laafin rẹ lasiko ipade alaafia kan to ṣe pẹlu awọn Fulani darandaran atawọn agbẹ. O ni niwọn igba toun ti gba awọn Fulani naa tọwọtẹsẹ lasiko ti ọpọlọpọ awọn ori-ade n le wọn jade kuro niluu wọn, ko gbọdọ nira fun awọn naa lati gbe igbesẹ ti yoo mu alaafia wa laarin ilu Iwo.

Gẹgẹ bi kabiesi ṣe sọ, “Emi mọ pe ọdaran yatọ si iran, ko si iran ti ko ni ọdaran, idi niyẹn ti n ko fi le pe gbogbo awọn Fulani darandaran ni ọdaran, ṣugbọn ẹyin naa gbọdọ gbe igbesẹ ti yoo jẹ kawọn eeyan mọ iyatọ laarin ẹyin atawọn to n da wahala silẹ.

“Mo mọ pe ọkan pataki lara iran to le ba wa gbogun ti wahala eto aabo lorileede yii ni iran Fulani, idi ni pe inu igbo lẹ n gbe, ẹ mọ awọn ajeji ti wọn n gba’nu igbo wọnu ilu laarin oru, ẹ mọ aṣiri wọn, ẹ si le fi to awa ori-ade leti nitori awa la sun mọ yin ju.

“O ti to asiko bayii ki ẹ jawọ ninu kiko awọn maaluu yin jẹko oloko ka, ko sẹni ti ẹ ba oko rẹ jẹ ti inu rẹ yoo dun, a si n ka awọn eeyan wa lapa ko ni, ẹ ba awọn eeyan yin sọrọ, ko sẹni ti ko le fa wahala.

“Ko too di pe ijọba maa gbe ofin to lagbara silẹ fun yin, ẹ tete ba ara yin sọrọ, ẹ ko awọn maaluu yin soju kan ṣoṣo, ẹ jẹ kawọn ọmọ yin lọ maa ja koriko wa fun wọn dipo ki wọn lọọ maa ba oko oloko jẹ kaakiri.

“Emi o fẹ wahala lorileede yii rara, bẹẹ ni n ko fẹ wahala niluu Iwo, mo ti gba yin nigba ojo, ẹyin naa ẹ gba mi nigba ẹẹrun. Mo ko yin mọra, gbogbo nnkan ti ẹ ba fẹ la maa ṣe fun yin, ẹ ko awọn maluu yin soju kan”

Ẹni to ṣoju kọmiṣanna ọlọpaa Ọṣun nibi ipade apero naa, ACP Obbo Ukam, sọ pe alaafia nikan ni ọpakutẹlẹ idagbasoke to ba fẹẹ wa nibikibi, o ni dipo ki awọn araalu maa ṣedajọ lọwọ ara wọn, ki wọn maa fi ẹjọ Fulani darandaran to ba fi ẹran jẹ oko wọn sun ọlọpaa tabi awọn ori-ade.

Bakan naa ni alaga ipade naa to tun jẹ Kọmiṣanna feto ọgbin nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Dayọ Adewọle, sọ pe laipẹ nijọba yoo ṣepade pọ pẹlu awọn tọrọ kan lati buwọ lu ohun ti yoo jẹ ijiya fun ẹnikẹni to ba ko maaluu jẹ kaakiri nipinlẹ Ọṣun.

Gbogbo awọn ori-ade, awọn Fulani, awọn Bororo, awọn agbẹ atawọn mi-in ti wọn wa nibẹ ni wọn gboriyin fun Ọba Akanbi lori igbesẹ naa, ti wọn si sọ pẹlu idaniloju pe yoo mu ayipada nla ba nnkan niluu Iwo ati agbegbe rẹ.

Leave a Reply