Ọkẹ aimọye dukia ṣegbe sinu ijamba ina lọja paati n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Beeyan ba de ọja Ararọmi, iyẹn ọja Isọ Paati to wa laduugbo Agodi, Gate, n’Ibadan bayii, aanu aje yoo ṣe oluwa ẹ nitori bi ina ṣe jo ọkẹ aimọye ọja ti owo wọn ki i ṣẹgbẹ miliọnu naira kekere guruguru.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meji oru nijamba ọhun bẹrẹ nigba to jọ pe waya ina ẹlẹtiriki ṣana lati inu ṣọọbu kan ti ina si tibẹ ṣọ.

Lọgan ni ina ti ṣọọbu yii ran mọ awọn to fara ti i, to si ṣe bẹẹ ran ọpọlọpọ ṣọọbu ninu ọja naa.

Toun ti bi iṣẹlẹ ọhun ṣe jẹ aarin oru to, a gbọ pe lati nnkan bii aago mẹrin aabọ oru lawọn ontaja lọja yii ti de sibẹ, ti wọn si n sa ipa wọn lati pana ọhun, bo tilẹ jẹ pe igbiyanju wọn ko seso rere nitori yatọ si pe ọwọngogo omi pe wọn nija, ina ọhun lagbara kọja agbara wọn.

Bi agbara ina yii ṣe pọ to paapaa ko jẹ ki iyanju ti wọn n gba lati ko awọn ọja wọn kuro ninu ṣọọbu, ki wọn le daabo bo o lọwọ ina, seso rere.

Awọn ọja to le tete gbina bii taya mọto ati ọili to pọ ninu awọn kan to wa ninu awọn ṣọọbu wọnyi lo tubọ mu ki ijamba ina ọhun  buru to bẹẹ.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ ti wọn pada pe paapaa lati waa pana yii ko ri agbara sa to bẹẹ pẹlu bi mọto wọn ko ṣe rọna ba de ibi ti ina ti n jo gan-an.

Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ero ọja yii ṣe ṣalaye fakọroyin wa, irin ti awọn panapana rin ki wọn too le yi ọpa omi ti wọn fi n pana de ibi ti ina ti n jo ko din ni irin iṣẹju marun-un.

O waa rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ọyọ lati ran awọn ara ọja naa lọwọ, paapaa, awọn to padanu dukia wọn sinu iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply