Ọkọ epo to gbina fọpọ ẹmi ṣofo loju ọna Ileṣa si Akurẹ

Florence Babaṣọla

Titi asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to mọye eeyan to ku ninu ijamba ọkọ to gbina ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lorita Ẹrin-Ijeṣa, to wa loju-ọna Ileṣa si Akurẹ.

Mọto nla kan to gbe diisu (diesel) la gbọ pe o deede fẹgbẹ lelẹ loju titi, ti gbogbo diisu inu ẹ si danu, loju ẹsẹ naa lo gbina, to si bẹrẹ si i ran mọ awọn mọto to wa lẹyin rẹ.

Bi awọn ọkọ to wa lọọọkan ṣe n sẹri pada, ko ṣee ṣe fun awọn mọto to tẹle tirela yii, paapaa, mọto bọọsi elero mejidinlogun to wa lẹyin rẹ gan-an lati sa pada.

Wahala yii fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ loju ọna yii nitori ko si mọto kankan to le kọja lasiko ti ina naa n jo lọwọ.

Idi niyi ti awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ-ojuupopo ti wọn sare de sibi iṣẹlẹ naa fi n dari awọn ọkọ gba ọna Ipetu-Ijeṣa.

Gbogbo awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni wọn n sọ pe ko ti i si ẹni to le sọ iye ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ nitori lojijo ni wahala naa ṣẹlẹ, ti onikaluku si sa lugbo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi ijamba naa mulẹ, ṣugbọn oun naa ko ti i le sọ iye awọn to jona nibẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: