Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe Jubilee, niluu Ikarẹ Akoko, ti ran ẹnikan sọrun apapandodo, nigba t’awọn meji to tun kọ lu ṣi wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun nile-iwosan tí wọn ti n gba itọju lọwọ.
ALAROYE gbọ lati ẹnu awọn ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn pe ijanu ọkọ J5 ọhun lo daṣẹ silẹ lojiji, lasiko lasiko to n sọkalẹ oke nla kan ti wọn n pe ni alaboojuto, wa si ọna Jubilee, niluu Ikarẹ.
Wọn ni ere asapajude ti awakọ naa n sa lo ṣokunfa bi ko ṣe ri ọkọ naa dari mọ lẹyin ti bireeki rẹ kọ ti ko ṣiṣẹ mọ, to si ṣe bẹẹ lọọ kọ lu awọn ẹni ẹlẹni nibi ti wọn duro si jẹẹjẹ wọn.
Ọkan ninu awọn to ba wa sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Musina Ibrahim, ni ọkunrin gbajugbaja oniṣowo pako kan, ẹni tawọn eeyan mọ si Obama, ni ọkọ J5 naa kọkọ kọ lu nibi to ti n ra eeso to fẹẹ jẹ, to si ku loju-ẹsẹ.
Awọn meji yooku lo ni ori ko yọ, ṣugbọn ti wọn fara pa pupọ, awọn mejeeji ọhun lo ni wọn sare gbe lọ si ọsibitu ijọba, nibi ti wọn ti n gba itọju lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Nigba ti Ọga awọn ẹṣọ oju popo niluu Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Mukaila Saliu, n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun akọroyin ALAROYE, o ni loju-ẹsẹ ni Obama ti ku ni tirẹ, lẹyin ti ọkọ ti kọ lu u. Awọn meji yooku ti wọn fara pa lo ni awọn gbe lọ si ọsibitu ijọba to wa niluu Ikarẹ Akoko.