Ọkọ mi fẹẹ fi ibalopọ pa mi, mi o fẹ ẹ mọ-Ọlamide

Ọlawale Ajao, Ibadan

Kootu ibilẹ Mapo, n’Ibadan, ko yatọ si ile sinima ti wọn ti n wo ere aladun laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, nigba ti iyawo ile kan, Ọlamide Lawal, wọ ọkọ ẹ, Saheed Lawal, lọ siwaju adajọ kootu ọhun, o lọkunrin naa ti fẹẹ fi ibalopọ ba oun laye jẹ.

Obinrin ọlọmọ mẹta yii sọ pe yatọ si bo ṣe jẹ pe gbogbo igba lọkọ oun maa n ba oun laṣepọ lojoojumọ, ọmuti paraku tun lọkunrin naa, o si fẹẹ le mu itọ idi ẹ bi ko ba rọti mu tẹra ẹ lọrun lọjọ kan.

 

“Ọmọ mẹta la ti bi. Ko si leto kankan fawọn ọmọ yẹn, ki i tọju wọn, ki i tọju emi naa, afi ko maa ba mi laṣepọ ṣaa. Ọpọ igba gan-an ni ki i tọkan mi wa, to jẹ pe tipatipa lo fi maa n ba mi ṣe e”. Bayii l’Ọlamide sọrọ niwaju adajọ.

Bakan naa lo ṣapejuwe ọkọ ẹ gẹgẹ bii ọlẹ ọkunrin, nitori asiko to fi n ṣiṣẹ ko to nnkan lẹgbẹẹ asiko to fi n jokoo sile-ọti.

Olupẹjọ yii waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si ibaṣepọ ọlọdun mẹrinla to wa laarin oun pẹlu olujẹjọ nitori pe ibagbepọ oun pẹlu ọkunrin naa ti ka oun laya patapata.

O ni bi wọn ba ti tu igbeyawo awọn ka tan, kadajọ tun ba oun paṣẹ fun baba awọn ọmọ oun yii lati ma ṣe gbiyanju lati wa oun wa, bẹẹ ni ko gbọdọ pe nọmba ẹrọ ibanisọrọ oun.

Ṣugbọn Lawal sọ pe oun ko fara mọ pe ki opin de ba igbeyawo awọn.

Nigba to n rọ adajọ lati ba oun pẹtu si iyawo oun ninu, ki obinrin naa ma kọ oun silẹ, ọkunrin telọ yii kọju si iyawo ẹ, o si wi pe “mo ti yipada, mi o muti mọ. Mo ṣetan lati bẹrẹ igbe aye tuntun. Mo si ṣetan lati maa fawọn ọmọ mi lowo ounjẹ.

Olori igbimọ awọn adajọ kootu yii, Abilekọ S.M. Akintayọ, ti sun igbẹjọ naa si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun yii, fun idajọ.

O waa gba tọkọ-taya naa niyanju lati ma ṣe ba ara wọn ja nibikibi ti wọn ba ti rira wọn.

Leave a Reply