Ọkọ mi fẹẹ fi mi ṣoogun owo, mi o fẹ ẹ mọ- Helen

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Okitipupa ti tu igbeyawo ọlọdun mẹjọ to wa laarin obinrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Helen Akinruntan, ati ọkọ rẹ, Festus Akinruntan, ka latari ija gbogbo igba to n waye laarin wọn.

Abilekọ Helen lo kọkọ waa fẹjọ ọkọ rẹ sun ni kootu ọhun, to si ni oun fẹ ki wọn tu ibasepọ to wa laarin awọn mejeeji ka nitori pe ọpọ igba lọkunrin toun bimọ mẹta fun naa ti gbiyanju ati fi oun ṣoogun owo.

O ni ọpọlọpọ igba ni olujẹjọ ọhun maa n leri, ti yoo si tun maa halẹ pe oun fẹẹ fi oun gun ọsẹ owo.

Lẹyin eyi lo ni oun ṣakiyesi pe idin n jade lati oju ara oun ni kete ti awọn jọ ní ajọṣepọ tan loru lọjọ kan.

Iya ọlọmọ mẹta naa tun fẹsun kan ọkọ rẹ pe ki i bọwọ to tọ fawọn obi oun, o ni eebu ati epe ni i fi i ransẹ si wọn ni gbogbo igba dipo ko maa pọn wọn le gẹgẹ bii ana.

Olupẹjọ ni oun ti oun fẹ ni kile-ẹjọ naa tu igbeyawo awọn ka, ko si fun oun laaye lati maa tọju awọn ọmọ mẹtẹẹta to wa laarin awọn.

Ọjọ akọkọ ti kootu ti bẹrẹ ijokoo wọn ni Ọgbẹni Akinruntan to jẹ olujẹjọ ti yọju kẹyin, ṣe lọkunrin naa kọ ti ko tun wa mọ titi ti wọn fi pari igbẹjọ.

Aarẹ kootu ọhun, Alagba Ọmọtayọ Benson, ninu idajọ rẹ pasẹ pe ki wọn tu igbeyawo naa ka lẹyẹ-o-ṣọka, niwọn igba ti aridaju ti wa pe ko si ifẹ mọ laarin wọn.

O ni, olujẹjọ gbọdọ maa san ẹgbẹrun marun-un marun-un naira lori ọmọ kọọkan gẹgẹ bii owo ounjẹ wọn loṣooṣu, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira fun owo ileewe wọn ni saa kọọkan ati ẹgbẹrun lọna ogun naira gẹgẹ bii owo ọkọ ti wọn n wọ lọ si ibi ikẹkọọ wọn.

Alagba Benson tun pasẹ fun olupẹjọ lati da ẹgbẹrun meji aabọ ti wọn san fun owo-ori rẹ pada fun olujẹjọ.

 

Leave a Reply