Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ẹni ta a fẹẹ sun jẹ tẹlẹ to tun n fepo para lọrọ ọkọ mi, mi o nifẹẹ rẹ tẹlẹ, ẹbẹ rẹ pọ ni mo ṣe fẹ ẹ, ko to tun maa huwa idọti. Orin yii lo gbẹnu iyaale ile kan, Aishat Salman, nigba to n rawọ ẹbẹ sawọn adajọ kootu kọkọ-kọkọ to wọ ọkọ rẹ, Mohammed Raji Tẹslim, lọ pe ki wọn tu igbeyawo awọn ka, oun ko ṣe mọ. O ni ọkunrin naa huwa eeri, ati pe oun ko nifẹẹ rẹ nibẹrẹ pẹpẹ, nigba ti ẹbẹ pọ ni oun gba fun un, tawọn fi ṣe igbeyawo.
Kootu kọkọ-kọkọ Area 1, to fikalẹ sagbegbe Ìpàta Ọlọ́jẹ̀ẹ́, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọrọ yii ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa yii.
Olupẹjọ naa, Aishat, rojọ niwaju awọn adajọ pe latibẹrẹ pẹpẹ ni oun ko ti nifẹẹ ọkọ oun, sugbọn o ti wa ninu kadara pe awọn yoo di tọkọ-taya ni.
O ni niṣe lọkọ oun maa n fi orukọ oun yawo kiri lọdọ awọn ọrẹ oun, to si n ba oun loju jẹ kiri. Bakan naa lo tun ni o n ba awọn ọmọọṣẹ oun ati ọmọ to n gbe ọdọ awọn ni ajọṣepọ. Iyaale ile yii ni eyi to buru jai ninu ọrọ ọhun ni pe irọ to n bẹ lẹnu ọkọ oun ki i ṣe kekere, bo n ṣe n parọ naa ni yoo maa f’Ọlọrun ṣẹri.
Aishat ni oun ko nifẹẹ rẹ mọ rara, kọda, oun pẹlu ọkọ oun ko le duro sọrọ fun iṣẹju kan mọ nibi toun koriira rẹ de.
‘‘Ọmọ mẹrin ni mo bi fun un, mi o si le fawọn ọmọ mi silẹ sakata ẹ, ẹ ba mi pa a laṣẹ pe ko maa gbọ bukaata awọn ọmọ rẹ, ẹgbẹrun lọna ogun Naira ni mo fẹẹ maa gba lowo ounjẹ awọn ọmọ loṣooṣu, ko si maa sanwo ileewe wọn. To ba rẹ awọn ọmọ, ma a maa tọju iyẹn.
Olujẹjọ to jẹ ọkọ Aishat, Mohammed Raji Tẹslim, sọ fun adajọ pe oun ko setan lati rojọ lonii, ki kootu fun oun ni ọjọ miiran lati waa wi tẹnu oun.
Onidaajọ Ajibade Lawal, gba ẹbẹ olujẹjọ wọle, o sun igbẹjọ si ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.