Ọkọ mi n mugbo, o tun n halẹ iku mọ mi, mi o se mọ- Tawakalitu

Olu-theo Omolohun Oke-Ogun 

Niṣe lọrọ pakasọ ni kootu kọkọ-kọkọ kan to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja yii, nigba ti Abilekọ Tawakalitu Suleman rawọ ẹbẹ pe kile-ẹjọ fopin si ajọṣepọ to wa laarin oun ati ọkọ oun, Ọgbẹni Ayuba AbdulRasheed, latari oriṣiiriṣii ẹsun to ka si i lẹsẹ, o lọrọ ọkunrin naa ti su oun pata, oun o si le fara da a mọ.

Tawakalitu ni amugbo pọnbele lọkọ toun bimọ meji fun ọhun, gbogbo asiko to ba si fa igbo rẹ yo, ori oun lo maa n fi abọ rẹ si, o di ko maa kanra mọ oun, ko maa ba oun ja lai nidii.

Olupẹjọ naa to pera ẹ lọmọ bibi ilu Ibadan ṣalaye pe ilu Eko loun ati Ayuba ti pade lọdun diẹ sẹyin, ki ọrọ ifẹ too ṣẹlẹ laarin awọn, ti oyun si fi de, tọkunrin naa si fi ẹnu rẹ ṣeleri foun pe gbogbo nnkan toun ba n fẹ loun maa ṣe fun oun ti oun ba ti gba lati waa gbe lọdọ awọn mọlẹbi oun niluu Ṣaki.

O ni eyi lo sọ oun dero Ṣaki, lai mọ pe ẹlẹtan lasan lọkunrin toun n pe lọkọ yii. O ni ko tojọ ko toṣu ti wahala fi bẹrẹ laarin oun atawọn mọlẹbi rẹ, ti olujẹjọ naa ko ri nnkan ṣe si i.

O tun fẹsun kan an pe ki i gbọ bukata lori oun, koda owo ọsibitu ti wọn beere nigba toun bimọ akọkọ fun un, funra oun loun san an, ko si bikita rara foun atawọn ọmọ toun bi latigba naa.

Igbe aye adagbe adafa ninu ipọnju lo ni oun n gbe, eyi lo mu ki ifẹ rẹ yọ lọkan oun pata.

Yatọ siyẹn, o tun fẹsun kan ọkunrin naa pe oun atawọn mọlẹbi rẹ kọ lati lọọ yọju sawọn obi oun lati lọọ tọrọ oun bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

O ni niṣe lọkunrin naa tun n dunkooko mọ oun pe toun ba fi le kọ oun silẹ, oun maa ri i daju pe oun ṣeku pa ọkọ yoowu toun ba fẹ ni.

Esi balabala kan lọkọ ọhun n sọ nigba ti wọn bi i lere ero rẹ lori ẹsun tiyawo naa fi kan an. O ni iyawo oun ko ni dukia kankan ko too dele oun, ati pe oun fura si i pe nigba to bẹrẹ si i yan ale lo dẹni to n ko awọn dukia kan jọ, dukia ọhun lo fi n ṣakọ soun. O loun yọnda to ba loun fẹẹ kọ oun silẹ, ṣugbọn kile-ẹjọ paṣẹ lati jẹ kawọn ọmọ wa lakata oun baba wọn.

Ṣa, Alaga kootu naa, Onidaajọ Muritala Ọladipupọ, sọ pe ẹri ti fihan pe ajọṣe awọn mejeeji ko le wọ mọ, lo ba tu igbeyawo wọn ka. O ni ọkunrin naa le maa yọju sawọn ọmọ rẹ, o si gbọdọ maa fowo ounjẹ ati aṣọ wọn ranṣẹ deedee, ṣugbọn akata iya wọn ni kawọn ọmọ naa wa titi ti wọn yoo fi pe ọdun mẹsan-an.

 

Leave a Reply