Faith Adebọla
Ọwọ palaba awọn afurasi adigunjale mẹta kan, Famous Ogooluwa, ẹni ọdun mẹtalelogun, Ibrahim Ọmọniyi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati Taofeek Sọliu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti segi, awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko lo mu un lasiko ti wọn n ti oko ole kan bọ pẹlu awọn ẹru ẹlẹru ti wọn ji, ni wọn ba dero ahamọ.
Ṣe Yooba bọ, wọn ni ‘ijakumọ ki i rin lọsan-an, ẹni a bi ire kan ki i rin’ru’, bẹẹ gẹlẹ lọrọ awọn adigunjale naa ri, ni nnkan bii aago kan aabọ oru Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji yii, ni wọn lawọn afurasi naa n yọ kẹlẹ kọja lagbegbe Abijo GRA, n’Ibẹju-Lẹkki, l’Erekuṣu Eko, laimọ pe olobo ti ta awọn ọlọpaa ẹka Ẹlẹmọrọ, nipa ole ti wọn lọọ ja, tawọn yẹn si ti n dọdẹ wọn bọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, SP Benjamin Hundeyin, sọ ninu atẹjade kan to fi lede pe meji ninu wọn, Famous ati Ibrahim, lọwọ kọkọ ba, wọn lawọn ni wọn lọọ fọle onile kan laduugbo GRA ọhun, ti wọn si ji wọn lẹru ko.
Lara ẹsibiiti ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ibọn agbelẹrọ meji, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin kan, foonu Tecno kan, ati foonu ZAT Android kan.
Bẹẹ ni wọn ba owo lapo awọn mejeeji, wọn si bi wọn leere pe ibo ni wọn ti ri ibọn, iṣẹ wo si ni wọn n ṣe ti wọn fi dẹni n rin kọsẹ-kọsẹ kiri laajin oru, wọn o le fesi, niṣe ni wọn n kilolo, igba to ya ni wọn jẹwọ pe ole lawọn, wọn ni ibi kan laduugbo naa lawọn maa n lugọ si tawọn fi n ja awọn araalu lole.
Wọn tun jẹwọ pe ọwọ Taofeek lawọn ti maa n gba ibọn, oun lo si maa n ba awọn ra nnkan ija ati ọta ibọn nigbakuugba tawọn ba fẹe lọọ ṣiṣẹ buruku yii.
Wọn ba juwe ibi ti Taofeek n gbe ati bi wọn ṣe le ri i mu, n lawọn ọtẹlẹmuyẹ lọọ fi pampẹ ofin gbe e lẹyẹ-o-sọka. Wọn loun naa ti jẹwọ pe ni tododo, oun ki i ba wọn lọ soko ole, amọ oun loun n ba wọn ṣeto nnkan ija oloro ti wọn nilo, awọn si ti wa lẹnu iwa abeṣe naa, o ti tojọ mẹta kan.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Ọmọhunwa, ti paṣẹ pe ki wọn tubọ ṣewadii awọn afurasi yii daadaa. O ni ile-ẹjọ lawọn yoo ko wọn lọ lati lọọ jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin.