Oko ole ni Sodiq n lọ l’Ọta tọwọ fi tẹ ẹ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ọlọrun lo ni kawọn ọlọpaa to n ṣe patiroolu ni ikorita oko Ọbasanjọ to wa l’Ọta, nipinlẹ Ogun, wa lojufo, eyi ni ọwọ wọn fi ba ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Sodiq Ọladele, nibi toun atawọn ẹmẹwa ẹ, lasiko ti wọn n lọọ digunjale laṣiiri wọn tu.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un yii, ni iṣẹlẹ naa waye, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi.
Wọn ni ori ọkada lawọn afurasi adigunjale naa wa, ọkan ninu wọn gbe baagi dudu kan dani, niṣe lo pọn baagi naa mọra bii pe dukia iyebiye kan lo wa ninu ẹ, eyi lo fu awọn ọlọpaa to n ṣe patiroolu agbegbe naa, eyi ti DPO ẹka Onipanu ko sodi lara, ni wọn ba wawọ si ọlọkada naa pe ko duro.
Nigba to fi maa duro, niṣe lawọn mejeeji to wa lẹyin ọkada naa, ati ọlọkada ọhun bẹ danu, ọna ọtọọtọ ni wọn gba, niṣe ni wọn sa wọgbo.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa gba fi ya wọn, wọn si le eyi to gbe baagi dudu dani ninu wọn, iyẹn Sodiq, titi ti wọn fi ri i mu.
Nigba ti wọn yẹ baagi naa wo, wọn ba ibọn meji, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin kan, awọn oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii ati aake pompo kan. Nigba ti wọn bi i leere, o jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oko ole loun atawọn ọrẹ oun n lọ tawọn ọlọpaa fi da awọn duro.
Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn mu afurasi yii lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran. O ni ki wọn wa awọn to sa lọ naa titi wọn fi maa ri wọn mu.

Leave a Reply