Ọlawale Ajao, Ibadan
“Oniṣina paraku niyawo mi. O tun maa n ṣe ṣina pẹlu oyun ninu. Mo ka ọkunrin mọ on lori, bẹẹ oyun oṣu mẹrin wa ninu ẹ nigba yẹn.
“Nibi ti iwọsi ọhun gun mi de, ale iyawo mi yii tun n ba mi du oyun, o loun loun loyun inu iyawo mi, afigba ta a too ṣayẹwo ẹjẹ lẹyin ta a bimo, ti ayẹwo fi han pe emi ni mo lọmọ, lo too jawọ ninu wahala to n ba mi fa”.
Eyi lalaye ti baale ile kan, Abdul-Rasheed Ọlalere, ṣe niwaju igbimọ awọn adajọ kootu ibilẹ Ọja’ba to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.
Ọlalere sọrọ naa gẹgẹ bii awijare rẹ si ẹjọ ti iyawo ẹ, Maryam Abdul-Rasheed, pe ta ko o, pe ki ile-ẹjọ naa fopin si ibaṣepọ oun ati Ọlalare.
Obinrin naa sọ pe oun ko lẹjọ pupọ lati ro, ki ile-ẹjọ ṣaa fopin si igbeyawo awọn loun fẹ, nitori ọkunrin naa ko tọju oun daadaa, eyi si ti mu ki ìfẹ rẹ yọ lọkan oun patapata.
Olujẹjọ naa fara mọ ki ile-ẹjọ tu igbeyawo wọn ka, o ni niṣe loun paapaa n fara da gbogbo ẹgbin ti olupẹjọ fi n rẹ oun lara lati iye ọjọ yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn eeyan ba mi sọrọ lẹyin ti mo ka a mọ pẹlu ọkunrin, mo si dariji i, a tun jọ n gbe papọ gẹgẹ bíi tatẹyin wa.
“Ṣugbọn nigba to ya lo tun bẹrẹ si i ko ọkunrin kiri. Aṣa ale yiyan to ko yii lo mu ifẹ ẹ yọ lọkan mi patapata.
“Njẹ ẹ mọ nnkan to tiẹ waa mu inu bi mi patapata? Niṣe niyawo mi fẹẹ ba ale rẹ to ba a sun lọjọsi lọ. Iyawo mi ko si fi bo fun mi rara pe ifẹ ọkunrin yẹn wa lọkan oun.
“Bi ki i baa ṣe pe mo ka a mọ ibi to to ti palẹ ẹru rẹ mọ ni, iba kuku ti ko tọ ale rẹ lọ, ti wọn iba si ti jọ maa gbe gẹgẹ bii tọkọ-taya bayii.”
Niwọn igba ti awọn mejeeji ti fara mọ ki ile-ẹjọ tu igbeyawo awọn ka, igbimọ awọn adajọ kootu naa, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, ti fopin si ibaṣepọ tọkọ-taya naa gẹgẹ bii ololufẹ.
Olupẹjọ nile-ẹjọ yọnda ọmọ kan ṣoṣo to sọ igbeyawo naa pọ fun, wọn waa paṣẹ fun olujẹjọ lati maa san ẹgbẹrun marun-un marun-un naira loṣooṣu fun olupẹjọ gẹgẹ bii owo ti obinrin naa yóò fi máa tọju ọmọ naa.