Ọkọ Sẹkinat tawọn kan dumbu ni Ṣagamu n beere fun idajọ ododo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọgbẹni Isa Adesanya ti i ṣe ọkọ Sẹkinat Adeasanya tawọn kan dumbu lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja ni Moro, lagbegbe Odokekere, ni Ṣagamu, ti ni kijọba ba oun da si ọrọ naa, ki wọn wa awọn to pa iyawo oun jade, ki wọn si fi wọn jofin.

Ohun ti a gbọ ni pe idaji kutu ọjọ Satide naa ni arẹwa obinrin ti wọn n pe ni Sẹkinat yii fi ile ọkọ rẹ silẹ ni Ṣagamu ti wọn n gbe,  ile mọlẹbi ọkọ ẹ ti ko jinna sile tiẹ lo n lọ lati lọọ ba wọn dana ayẹyẹ igbeyawo ti wọn fẹẹ ṣe.

Awọn obinrin ile yooku ti wọn jẹ iyawo ninu ẹbi naa ti wa nibẹ, eyi lo fa a ti Ṣẹki naa fi kuro nile ni nnkan bii aago marun-un kọja iṣẹju mẹfa idaji, to fẹẹ lọọ ba wọn ṣiṣẹ olobinrin ile nile ẹbi ọkọ.

Afi bo ṣe ṣe kongẹ awọn janduku, a tilẹ gbọ pe awọn ẹruuku naa n jale nibi kan lọwọ ni lagbegbe naa.

Bi wọn ṣe ri Sẹkinat ni wọn da a duro, wọn gba foonu rẹ atawọn nnkan mi-in to gbe dani. Wọn da a dubulẹ wọn si fọbẹ si i lọrun, bẹẹ ni wọn ṣe dumbu rẹ, ti wọn si fọbẹ la ọna ọfun obinrin naa.

Ki wọn too dumbu ẹ yii, awọn araadugbo naa gbọ igbe iyaale ile yii nigba to n keboosi pe kawọn eeyan waa gba oun kalẹ lọwọ awọn janduku, to n ke pe ki wọn ma jẹ kawọn eeyan naa pa oun.

Awọn kan jade si i lati ran an lọwọ, wọn ni ṣugbọn bawọn ẹruuku naa ṣe ri i pe awọn eeyan ti n de ni wọn sare bẹ sori ọkada, ti wọn sa lọ.

Inu agbara  ẹjẹ lawọn to fẹẹ gba Sẹkinat silẹ ba a, wọn ri i pe o ti ku, ṣugbọn wọn gbiyanju gbe e de ọsinbitu, nibi ti dokita ti sọ fun wọn pe obinrin naa ti di oku.

Ọkọ rẹ, Ọgbẹni Isa Adesanya, ṣalaye pe ile aburo baba oun ni Sẹkinat n lọ lati ran wọn lọwọ ninu ina dida.

O ni bo ṣe kirun Asubaa tan laaarọ ọjọ naa to si wẹ fawọn ọmọ lo bọ sọna. Afi boun ṣe bẹrẹ si i gbọ ariwo pe nnkan ti ṣẹlẹ siyawo oun.

Isa tẹsiwaju pe awọn to tete jade lati ran an lọwọ lọjọ naa ri meji ninu awọn to kọlu u naa. O ni ọjọ Satide ọhun lawọn ti sinku Sẹki nilana ẹsin Islam, ṣugbọn oun ko fẹ kawọn to da oun loro mu un jẹ gbe, o ni gbogbo bo ba ṣe wu ko ri, afi kawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun tete bẹrẹ iwadii, ki wọn mu awọn to ṣẹka naa, ki wọn si ṣedajọ to yẹ labẹ ofin fun wọn.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni nigba ti wọn fẹẹ sin obinrin to ku naa ni wọn waa fi to awọn leti, nitori wọn nilo iwe ti wọn yoo fi ṣe akọsilẹ pe Sẹkinat Adesanya ti jade laye.

Teṣan Ogijo ni wọn ti lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, DPO ibẹ si ni ki wọn ma ti i sinku naa gẹgẹ bi Oyeyẹmi ṣe wi.

O ni ki wọn jẹ kawọn ṣe ayẹwo fun un lati mọ iru iku to pa a, ṣugbọn awọn ẹbi oku sọ pe ko si idi kankan lati ṣẹṣẹ maa wadii ohun to pa Sẹkinat, nitori o ti ku na, ko sohun tẹnikan le ṣe siyẹn, bẹẹ ni ẹsin Islam ko faaye silẹ pe keeyan maa wadii ohun to pa oku nigba to yẹ ki wọn gbe e sin gẹgẹ bii aṣẹ Ọlọun Allah.

Ṣa, ohun tawọn eeyan n sọ nipa iṣẹlẹ yii ni pe aabo ni ko si niluu mọ, to bẹẹ to fi di pe eeyan ko le jade nile laago marun-un idaji, eeyan o le rin lọsan-an gangan lai bẹru, ka ma ti i sọ pe tilẹ ba ṣu.

Awọn eeyan Moro sọ pe aabo ko si lọdọ awọn rara, wọn ni laarin Eko ati Ogun ni Moro wa,  ijọba si ti gbagbe awọn.

Wọn ni awọn janduku to ba daran l’Ekoo abi l’Ogun yoo sa wa si Moro, wọn yoo fara pamọ sibẹ, wọn yoo si pada maa da hilahilo silẹ laarin awọn.

Ṣa, bi ọwọ yoo ṣe ba awọn to pa Sẹkinat Adesanya, ti wọn yoo jiya ẹṣẹ wọn, lo jẹ baale rẹ logun bayii, ohun to si n beere naa ni idajọ ododo.

Leave a Reply