Ọkọ tẹ akẹkọọ mẹta, ọmọ baba kan naa, pa lori ọkada n’Igunsin

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn akẹkọọ ileewe girama mẹrin ni wọn pade iku ojiji ninu ijamba ọkada kan to waye niluu Igunṣin, eyi to wa laarin ọna marosẹ Ondo si Ọrẹ, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti ẹni karun-un wọn si wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun.
Gẹgẹ bi ohun ta a fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to jẹ mọlẹbi awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun, o ni awọn ọmọ to ku naa jẹ akẹkọọ to n ṣe idanwo aṣekagba lọwọ nile-iwe girama kan to wa lagbegbe Igunṣin.
O ni ọjọ ori eyi to dagba ju ninu awọn ọmọ mararun-un ọhun ko ti i ju bii ogun ọdun lọ, ijọba ibilẹ Ogoja, nipinlẹ Cross River, lo ni obi mẹrin ninu awọn ọmọ naa ti wa, nigba ti ẹni kan yooku jẹ ọmọ ilẹ Yoruba nibi.
Ni ibamu pẹlu alaye to ṣe fun wa, awọn mẹrin ti wọn jẹ ọmọ baba kan naa ni wọn kọkọ wa lori ọkada ọhun ti ọkan ninu wọn gun, wọn ti fẹẹ wọ igboro ilu Igunṣin tan ki wọn too gbe ọrẹ wọn kan to jẹ ọmọ Yoruba, leyii ti wọn fi pe marun-un lori ọkada kan ṣoṣo.
Ibi ti ẹni to gun ọkada ọhun ti n gbiyanju lati kọja lara ọkọ kan to wa niwaju wọn lo ti pade ọkọ miiran niwaju, eyi to tẹ mẹrin ninu wọn pa lẹsẹkẹsẹ. Ẹni karun-un wọn nikan lori ko yọ, ṣugbọn oun naa fara pa yannayanna.

Oku awọn mẹrẹẹrin ṣi wa ni mọṣuari ileewosan ijọba to wa niluu Ondo lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ, nigba ti ẹnikan to ṣi wa laye ninu wọn n gba itọju lọwọ lọsibitu yii kan naa.

Leave a Reply