Ọkọ Toyin Abraham sọko ọrọ sawọn to ni iyawo ẹ lo n gbọ bukaata ile wọn

Adefunkẹ Adebiyi

Lọjọ Mọnde to kọja yii ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ni oṣere tiata nni, Kọlawọle Ajeyẹmi, to jẹ ọkọ Toyin Abraham, ṣe ọjọọbi. N lo ba si fi mọto kan to ṣẹṣẹ ra ṣayẹyẹ ọhun, o gbe e sori ayelujara. Lawọn aye ba ni oun kọ lo ra mọto naa, o daju pe iyawo rẹ lo ra a fun un.

Oriṣiiriṣii ọrọ to tọka si pe ọkunrin naa n jọla Toyin, Iya Ire, to fẹ, lo jẹ ko maa dan ju ti tẹlẹ lọ lo pọ loju opo ayelujara rẹ.

Awọn mi-in tilẹ ti n sọ ọ tipẹ pe Toyin Abraham lo n gbọ bukaata inu ile Kọla, wọn ni bobinrin naa ṣe n lọ siluu oyinbo ati Dubai lo n mu Baba Ire ati ọmọ to ti bi tẹlẹ ko too fẹ Toyin ( Tọpẹ) dani, bẹẹ ni awọn eeyan naa n fi ọla Toyin ṣara rindin ni ti wọn.

Eyi naa lo si fa a ti Kọla fi fi ọrọ kan soju opo Instagraamu rẹ, nibi to ti sọ pe, “Lọdun yii, awọn alaidaa eeyan yoo ku lori ọrọ mi, nitori ẹ o ti i ri nnkan kan. Ọlọrun mi n ṣiṣẹ lọwọ.”

Toyin paapaa koro oju sawọn eeyan to n sọ pe ọkọ rẹ ko le da bukaata gbọ, o ni nnkan to buru jai ni bi wọn ṣe n ro pe beeyan ba ṣe lokiki to lo ṣe n lowo to.

Iya Ire ṣalaye pe ọkọ oun niṣẹ gidi to n ṣe, o si n gbọ bukaata oun atawọn ọmọ rẹ gẹgẹ bii baba gidi ninu ile. Fun ẹnikẹni lati ro pe oun loun ra mọto fun un tabi pe ọla oun lo fi n ṣe gbogbo nnkan ko tọna, Toyin ni ko si ri bẹẹ rara.

O loun ko ni i kawọ gbera kawọn eeyan kan maa fabuku kan ọkọ oun bii eyi, ki kaluku yaa ṣọra ṣe lọdun tuntun yii o.

Iwadii fi han pe ohun to jẹ kawọn kan maa ro pe Kọla Ajeyẹmi ko ni i nnkan kan ni pe okiki rẹ ko kan to bayii nigba ti ko ti i fẹ Toyin Abraham. Nigba to si foju han pe ọkunrin naa ni Toyin loyun fun nigba naa paapaa, ọpọ eeyan lo ya lẹnu, wọn ni ọkunrin naa kere si Toyin ninu ọpọ nnkan.

Awọn mi-in fi ti Adeniyi Johnson ti Toyin kọkọ fẹ ṣakawe, wọn ni ko sẹni to mọ Adeniyi tẹlẹ, afigba to fẹ Toyin Abraham lokiki rẹ bu jade. Wọn ni ọla obinrin naa lo ran Kọla to bi Ire fun bayii. Ṣugbọn Kọla funra ẹ ti ni ẹjọ oun ni yoo pa awọn to n ro o ka, iyawo rẹ naa si ti ni k’Ọluwa ba oun waṣẹ fawọn to n sọrọ ọkọ oun laidaa.

Leave a Reply