Faith Adebọla
Inu ayọ ati idunnu gidi ni minisita feto iṣuna nilẹ wa tẹlẹ, Abilekọ Ngozi Okonjo-Iweala, wa bayii, latari bi wọn ṣe kede rẹ lọjọ Aje, Mọnde yii, pe oun lo jawe olubori, oun si ni wọn yan sipo ọga agba Ajọ Okoowo Agbaye (World Trade Organisation).
Iroyin ayọ naa ti wọn fi lede lori atẹ ayelujara abẹyẹfo (tuita) ajọ ọhun sọ pe igbimọ alaṣẹ to ga ju lọ ajọ naa ti panu-pọ, wọn si ti fọwọ si i pe Ngozi Okonjo-Iweala lati Naijiria kunju oṣuwọn, oun si lawọn yan lati wa nipo ọga agba keje ti ajọ naa.
Itan nla ni iyansipo yii fi balẹ, tori yatọ si pe igba akọkọ ree ti ọmọ orilẹ-ede Naijiria yoo wa nipo nla yii, igba akọkọ naa tun ree ti obinrin yoo di ipo yii mu.
Tori bẹẹ, bi iṣẹ ikini ku oriire ṣe n rọjo latari iyansipo tuntun rẹ, bẹẹ lawọn eeyan jannkan-jannkan nilẹ wan n kan saara si ọmọ bibi ipinlẹ Delta yii, ti wọn si n gboṣuba fun un pe idunnu ati nnkan iyi mi-in lo tun ṣẹlẹ si orilẹ-ede Naijiria lawujọ awọn orilẹ-ede agbaye lọwọ yii.
Aarẹ orileede wa, Mohammadu Buhari ti gboriyin fun obinrin yii, ninu atẹjade kan lati ọfiisi rẹ, o ni oun ni idaniloju pe Ngozi yoo fakọ yọ nipo tuntun ti wọn yan an si, yoo si gbe ogo orileede wa ga; yoo tun lo imọ ati iriri rẹ lati mu ki okoowo agbaye lati orilẹ-ede kan si omi-in gberu si i.
Awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin lọkan-o-jọkan naa ti n kan saara si i, wọn si n ba a yọ pẹlu.
Abilekọ Okonjo-Iweala naa ti sọrọ lori iyansipo tuntun yii, o ni inu oun dun dẹyin, oun si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani nla to bọ soun lọwọ yii, pẹlu ileri pe oun yoo ṣe gbogbo ohun to ba yẹ lati mu ki iṣoro ati ojojo ti arun Korona mu ba okoowo agbaye di nnkan igbagbe laipẹ.